Yor 413
Yor 413
Ojúṣe Akẹ́kọ̀ọ́
Ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kòọ́ ni pé o gbọ́dọ̀ ka àwo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó wà nínú kọ́ọ̀sì yìí dáadáa, kí o sì rí
i pé ó yé ọ yékéyéké. Ìdí èyí ni pé o gbọ́dò mọ àṣà Yorùbá dunjú, kí ó sì tún dáńgájíá láti le
ṣàlàyé ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àṣà ajẹmọ́ṣẹ̀ṣe àti àṣà àrídìmú Yorùbá.
Ìgbéléwọ̀n Akẹ́kòọ́
Oríṣìí ọ̀nà ìgbéléwọ̀n méjì ló wà. Ìkínní ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí iṣẹ́ àmúṣe èyí tó kó ìdá ọgbọ̀n (30%) nínú
ọgọ́rùn-ún. Ìkejì ni ìdánwò, èyí tí akẹ́kọ̀ọ́ yóò jókòó ṣe lẹ́yìn tí o bá ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tán. Ìdá
àádọ́rin (70%) nínú ọgọ́rùn-ún ni ìdánwò yìí. Àpapọ̀ bí o fi ṣe dáadáa sí nínú ìdánrawò tàbí
ìdánwò ọ̀nà méjèèjì yìí ni yóò júwe tàbí sọ àpapọ̀ máàkì rẹ̀ nínú kọ́ọ̀sì yìí.
Ìdánwò Àṣekágbá
Èyí ni ìdánwò tí o ó jókòó ṣe lẹ́yìn tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bá ti parí. Má ṣe gbàgbé pé ìdá àádọ́rin (70%) ni
ìdánwò yìí kó nínú ọgọ́rùn-ún.
Ìgbéléwọ̀n Máàkì
1.0. Ìfáárà
Gbogbo ẹ̀yà lágbàáyé ló ni àṣà tí wọ́n ń tẹ̀lé tó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí atọ́nà fún wọn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ni ẹ̀yà
Yorùbá ní tire tó jẹ́ kí tèwe tàgbà wọn mọ nǹkan tó tọ́ àti tó yẹ láti ṣe. Àkóónú àṣà Yorùbá pọ̀
débi pé a lè sọ pé kò lóǹkà. Àṣà wà látorí ìbágbépọ̀ láwùjọ títí tó fi dórí ìgbéyàwó,
ìsọmọlórúkọ, ẹgbẹ́, ọ̀gbà, iṣẹ́ ìbílẹ̀, ìranraẹnilọ́wọ́, oúnjẹ, aṣọ-wíwọ̀, ìtọ́jú ara-ẹni tàbí oge-
ṣíṣe, ẹ̀kọ́-ilé, abbl. Yàtọ̀ sí pé a óò sọ̀rọ̀ lórí mélòó kan nínú kọ́ọ̀sì yìí, ìyànjú yóò wáyé láti pín
gbogbo wọn sí ìsọ̀rí méjì tí a lè pè ní àṣà ajẹmóṣẹ̀ṣe àti àṣà àrídìmú. Nínú ìdánilẹ́kọ̀ó yìí ni a
óò ṣàlàyé nǹkan tí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan jẹ́, kí wọn bàá lè yé mùtúmùwà dáadáa.
4.0. Ìdánilẹ́kọ́ọ̀
i. Àṣà Ajẹmọ́ṣẹ̀ṣe
Kín ni àṣà?
Àṣà ni ohun ti ó ṣe àfihàn ìran kan, ọ̀nà ìgbé-ayé àwọn ìran, èèyàn tàbí olùgbé àwùjọ kan; ìṣesí
tàbí ìhùwàsí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀; ìgbagbọ́ wọn, ẹ̀sìn wọn, oúnjẹ wọn, ìṣẹ̀ṣe wọn, ìmúra tàbí ọ̀nà
ìwọṣọ wọn tó fi mọ́ irúfẹ́ oúnjẹ tí wọn ń jẹ (Abubakre, 2019: 14 – 15). Ó yẹ kí n fi kún un fún ọ
pé, èdè tí wọn ń sọ náà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àṣà irúfẹ́ àwọn ènìyàn tàbí àwùjọ bẹ́ẹ̀. Ìṣẹ̀ṣe làgbà ní
ìbámu pẹ̀lú èrò àwọn Yorùbá, èyí sì máa ń jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣesí wọn. Ifá tilẹ fi ìdí pàtàkì rẹ̀
múlẹ̀ pe:
Ẹsẹ-Ifá òkè yìí fi í hàn pé ìṣẹ̀ṣe ṣe pàtàkì láwùjọ Yorùbá. Ó yẹ ká bi ara wa léèrè àwọn àṣà
Yorùbá wo ló wà lábẹ́ ìsọ̀rí ajẹmọ́ṣẹ̀ṣe. Àwọn àṣà tí a le kà sí ìṣẹ̀ṣe nìwọ̀nyìí:
Ìgbéyàwó
Ìsìnkú
Ọdún-ìbílẹ̀
Ìsọmọlórúkọ
Orin ìbílẹ̀
Oyè-jíjẹ
Ọba-jíjẹ
Iṣẹ́ ìbílẹ̀
Oúnjẹ ìbílẹ̀
Oge-ṣíṣe
Aṣọ-wíwọ̀
Òwò-ṣíṣe
Ẹ̀sìn
Ìranraẹnilọ́wọ́
Ìṣèlú ibílẹ̀
Ẹgbẹ́/ọ̀gbà-ṣíṣe
Ẹgbẹ́ awo
Ọ̀rẹ́-yíyàn
Ìmùlẹ̀, abbl.
Lára àwọn ìṣẹ̀ṣe tó wà lókè la lè pín sí ìṣẹ̀ṣe ajẹmáyẹyẹ àti ajẹmọ́bọ (èyí tó jẹmọ́ Òrìṣà). Díẹ̀ nínú
àwọn tó jẹmọ́ ayẹyẹ ni:
Ìgbéyàwó
Ìsìnkú
Oyè-jíjẹ
Ọba-jíjẹ, abbl.
Ẹgbẹ́ awo
Ọdún ajẹmọ́bọ
Ìṣègùn Ètutù-ṣíṣe
Ní abẹ àṣà tó jẹ mọ́ ìṣẹ̀ṣe ni gbogbo àwọn nǹkan tí a ti mẹ́nu bà lókè wọ̀nyí wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀
ìgbéayé àwọn ìran Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ náà ló wà títí dòní bó tilẹ jẹ́ pé àṣà ìgbàlódé ń fa àyípadà díẹ̀díẹ̀
bá wọn.
Aṣọ
Ilé
Epo
Oúnjẹ
Nǹkan aṣaralóge
Ọtí
Iṣẹ́-ìbílẹ̀
Ẹgbẹ́ awo, abbl.
Àwọn nǹkan tí a kà sókè yìí ni ó wà láwùjọ Yorùbá. Ìgbésẹ̀ wà lórí bí wọ́n ṣe ń ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.
Ká tó rí aṣọ, o lọ́nà tí wọ́ ń gbé e gbà, bẹ́ẹ̀ ni ó ní ìgbésẹ̀ tí wọn ń gbé ká to le rí epo. Wọ́n ní kí
iṣu tó diyán, a gúnṣu lódó, bẹ́ẹ̀ ni kí agbàdo tó dẹ̀kọ, a lọ̀ wọ́n papọ̀. Gbogbo àwọn tó jẹ mọ́ aṣà
àrídìmú ló ni ọ̀nà tí wọ́n ń gbé wọn gbà kí wọn tó dé ipò tí wọ́n wà. A sì tún gbọdọ̀ mọ̀ pé ibùdó
àti ẹni tó lè ṣe wọn yàtọ síra wọn.
5.0. Ìsọníṣókí
Àsà ni a lè pín sí èyí tó níí ṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀ṣe àti èyí tó jẹ́ àrídìmú. Nínú àṣà ajẹmọ́ṣẹ̀ṣe la ti rí
ìgbéyàwó, ìsìnkú, ọdún ìbílẹ̀, ètùtù ṣíṣe, abbl. Bẹ́ẹ̀ la rí iṣẹ́ ìbílẹ̀, ilé-kíkọ́, aṣọ-wíwọ̀, oúnjẹ, abbl
nínú àṣà àrídìmú.
Ọlájubù, O. (1978) Ìwé Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá, Ìkẹjà: Longman Nigeria Ltd.
2. Módù Kejì
Ìṣẹ̀ṣe Ajẹmáyẹyẹ àti Ajẹmọ́bọ: Ọdún Ìbílẹ̀
1.0. Ìfáàrà
Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, a óò ṣàlàyé lórí àṣà ajẹmáyẹyẹ àti ajẹmọ́bọ ní àwùjọ Yorùbá. Ìṣẹ̀ṣe
ajẹmáyẹyẹ ni àṣà tí kò ní ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tàbí ètùtù nínú. Ìṣẹ̀ṣe ajẹmọ́bọ ni a lè pè ní àṣà tó jẹmọ́ ẹ̀sìn,
ètùtù, òrò, àti awo ṣíṣe. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yóò jẹ́ kó yé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn pé kí ṣe gbogbo àṣà Yorùbá ló
níí ṣe pẹ̀lú Òrìṣà bíbọ.
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
Ìṣẹ̀ṣe Ajẹmáyẹyẹ
Àwọn àṣà tó jẹmọ́ ayẹyẹ pọ̀ lọ jàrá láwùjọ Yorùbá. Àwọn tí a óò mẹ́nubà ni:
ìdánilárayá
eréṣùpá
ìgbéyàwó
ìsọmọlórúkọ
orin etíyẹrí
àpàlà
rárá
àdàmọ̀
dadakùádà
alámọ̀
ìsìnkú, abbl.
Gbogbo àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí àti àwọn mìíràn ló jẹmọ́ ayẹyẹ nílẹ̀ Yorùbá. Jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá
ni wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó, ó kàn jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń ṣe é níbì kan lè yàtọ̀ sí ti ibòmíràn.
Káàkiri àwùjọ Yorùbá ni eréṣùpá ti máa ń wáyé; bákan náà ni àwọn Yorùbá kúndùn ètò
ìsọmọlórúkọ. Ẹ̀wẹ̀, oríṣiríṣi orin ajẹmáyẹyẹ kò gbẹ́yìn láwùjọ Yorùbá. Àwọn Yorùbá kò fi ayẹyẹ
ìsìnkú ṣeré rárá, àgàgà tó bá jẹ́ òkú àgbà tí wọ́n ń dà á pè ní òkú-ẹ̀kọ. Ìgbésẹ̀ tó mọ́yán lórí ni wọ́n
máa ń ní fún ayẹyẹ kọ̀ọ̀kan.
Ìṣẹ̀ṣe Ajẹmọ́bọ
Oríṣìí ìṣẹ̀ṣe tó wà láwùjọ Yorùbá tí a kà sí ajẹmọ́bọ ni ọdún ìbílẹ̀ tí wọ́n fi ń rántí àwọn Òrìṣà àti
àwọn akọni ìgbàanì láwùjọ Yorùbá. Àwọ ètutù lọ́kanòjọ̀kan àti ọdún orò náà kò gbẹ́yìn lára ìṣẹ̀ṣe
ajẹmọ́bọ. Lára irúfẹ́ ìṣẹ̀ṣe wọ̀nyí ni a tọ́ka sí ní ìsàlẹ̀ yìí:
Ọdún Òkèè’Bàdàn
Ọdún eégún
Ọdún Ọ̀sanyin ní Osùn-ún Èkìtì
Ọdún Ọ̀lẹ̀lẹ̀ ní Ògbómọ̀ṣọ́
Ọdún Orò ní Ìsẹ́yìn
Ọdún Ògún ní Irè Èkitì àti ìlú Oǹdó
Ọdún Ẹ̀yọ̀ ní Èkó
Ọdún Ṣàngó ni ….?
Ọdún Ẹ̀lúkú ní Òkè-Igbó, Abẹ́òkúta àti Ìkòròdú
Ọdún Baraàgbọn ní Èsìẹ́
Ọdún Ojú-odó ní Igbóńlá
Ọdún Erinlẹ̀ ní Ìlobùú
Ọdún Ọbàlùfọ̀n ní Ẹ̀rìn-Ilé, Ẹ̀rìn-Ọ̀ṣun àti Ìdó-Ọ̀ṣun
Ọdún Orìṣà Ògìyán ní Èjìgbò
Ọdún Òrìṣà Pópó ní Ògbómọ̀ṣọ́ àti Ìwó
Gbogbo àwọn Òrìṣà wọ̀nyí ni àwọn Yorùbá máa ń bọ lóòrèkóòrè àti ní ọdọọdún kí wọn bàá lè rí
ojú rere wọn. Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá ni pé àwọn Òrìṣà wọ̀nyí yóò jẹ́ kí nǹkan máa lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀
Fún wọn.
5.0. Ìsọníṣókí
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí dá lórí ̣ìṣẹ̀ṣe Láwùjọ Yorùbá nípa ti ayẹyẹ àti ẹ̀sin. Oríṣiríṣi ayẹyẹ tó ń wáyé ní ọ̀pọ̀
ìlú nílẹ̀ Yorùbá la ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lé lórí pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ.
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
Ìpín Kìíni: Orin Yorùbá
Ọ̀kan-ò-jọ̀kan orin ló sì wà ní ìkáwọ́ àwọn Yorùbá. Àmúlùúdùn ni orin jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ló si jẹ́
adàlúrú, ṣé orin ló kúkú ń ṣáájú ọ̀tẹ̀. Oríṣìí ọ̀nà méjì ni a lè pín orin Yorùbá tó jẹ́ ti àbáláye sí:
i. orin ajẹmẹ́sìn
ii. orin ayẹyẹ
i. Orin ajẹmẹ́sìn ni orin tí wọ́n ń kọ nídìí Òriṣà, yálá nígbà ọ̀sẹ̀ tàbí ọdún Òriṣà. Irúfẹ́ orin
yìí wọ́pọ̀ láàrin àwọn Yorùbá. Orin Ọ̀sanyin ni wọ́n fi ń ṣọdún Òriṣà Ọ̀sanyin ni ilú
Osùn-ún Èkìtì (Orímóògùnjẹ́, 1986). Orin Ògún ni wọ́n ń kọ nígbà ọdún Ògún ní
agbègbè Ìjerò Èkìtì (Aládésòfi, 1986). Orin àgbọn ni wọ́n ń kọ ní Ilé-Ifẹ̀ ní àkókò ọdún
Àgbọn. Àwọn Olórìṣà Ọbàtálá náà ní orin tiwọn nídìí Òòṣà wọn. Bí àpẹẹrẹ:
Àwọn onífá náà máa ń kọrin ní ọ̀kan-ó-jọ̀kan láti mú orí Ọ̀rúnmílà wú. Nílé Ifá, a lè gbọ́ irúfẹ́
orin yìí:
Gbogbo ìbọ tó wà nílẹ̀ Yorùbá, àti ọdún ìbílẹ̀ pátá poo ló ní oríṣiríṣi orin tí wọ́n ń kọ sí wọn ní
ákókò tí ó bá yẹ kí ó wáyé. Bí ewé rúmọ ni orin ayẹyẹ pọ̀ nílẹ̀ Yorùbá. Àwọn orin tó wà fún
ayẹyẹ kò wá fún ìbọ kankan, àwọn Yorùbá máa ń fi àwọn orin wọ̀nyí dárayá láti fi pa ìrònú rẹ́.
Láàrin àwọn Ọ̀yọ́ Yorùbá, Ẹ̀gbádò àti Ẹ̀gbá ni orin Etíyẹrí ti gbalẹ̀ (Ìṣọ̀lá, 1977; Àjàmú, 1977).
Wọ́n ń pe orin yìí ní Etíyẹrí nítorí pé àwọn Ọ́kọrin yìí máa ń gbé ère kan tó ní etí ṣàgìlà bí etí
ehoro sórí. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àtàmpàkó kò sí, ìká dẹ̀mú, etí kò sí orí dàpólà igi. Lóòótọ́ bí kò
bá sí etí, orí kò ní lẹ́wà olóókan. Àwọn ọ̀kọrin yìí máa ń ṣe bí oní–wéré(oní-wéré), wọ́n máa ń
tojú ilé kan dè èkejì. Kò sí ẹni tí wọn kò lè fi ṣe yẹ̀yẹ́. Gbogbo nǹkan tó ń lọ ní àwùjọ ni wọ́n
máa ń fi orin wọn sùn.
Orin agbè (Àlàbá, 1985) náà jẹ́ ọ́kan lára orin ayẹyẹ; èyí sì wọ́pọ̀ lọ́dọ́ Yorùbá Ìbàràpá; Òkè-
ógùn àti Ìgbómìnà. Agbè ńlá tí wọ́n so owó ẹyọ mọ́ lára ni wọ́n máa ń lù sí orin; èyí ló sì jẹ́ kí
wọn pè é ní orin agbè. Àwọn ọ̀kọrin yìí náà tún máa ń pidán lójú agbo. Nǹkan tó ń lọ ní àwùjọ
ni wọ́n máa ń fi orin gbé jáde.
Olele fìdí múlẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn Ìjẹ̀ṣà (Fádọ̀gbà; 1972, Ilésanmí, 1974). Wọ́n máa ń lo olele fún
àṣeyẹ, ẹnikẹ́ni tó bá ní ayẹyẹ ì ṣe ló lè pè wọ́n láti wa ṣeré fún wọn. Oríṣìí olele mẹ́ta ló wà:
olele adán, olele àdàrodò àti olele wáewáe. Abẹ́nà ìmọ̀ wa sọ pé olele adán ni ó dùn í gbọ́ létí ju
àwọn yòókú lọ.
Eré Obitun: jẹ́ orin tí ọmọbìnrin tó bá ń lọ ilé ọkọ máa ń kọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eré obìnrin ni, àwọn
ọkùnrin ni onílù wọn. Àwọn Òǹdó ló ni eré yìí.
sí i, ṣùgbọ́n ní báyìí, wọ́n ti ń lu ìlù sí i.
Eré Bàlúù: jẹ́ eré tí àwọn obìnrin máa ń ṣe ní ìlú Ìlọrin. Orin bàlúù farapẹ́ eré dadakúàdà dáadáa
tí a bá fi àkóónú inú rẹ̀ wé ti dadakúàdà.
Eré Agbè: jẹ́ eré ní ilẹ̀ Ìbàràpá àti ní ìlú Ìlọrin. Agbè ni wọ́n máa ń lù nínú eré yìí.
orin agbélégbé: Alí Owé Yorùbá, àwọn Kabba ló ni (Médùbí; 1989); ayẹyẹ náà ni wọ́n ń lo orin
yìí fún. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Ilọrin àti Ìgbómìnà kúndùn láti máa lo Dàdàkúàdá fún ọ̀kan-ò-jọ̀kan ayẹyẹ
(Afọlábí, 1977).
Orin Kete: ni a mọ̀ mọ́ Yorùbá Ọ̀yọ́. Àwọn ọkùnrin ló ń ṣeré kete. Bí olórí wọn ti ń lé orin bẹ́ẹ̀
ni àwọn elégbè yóò máa gbè é bí wọ́n ti ń lu ìlù bẹ̀ǹbẹ́ sí i.
Orin Apẹ́pẹ́: ni ti ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Ọparun pẹlẹpẹlẹ tí wọ́n ti là sí tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n fi ń lu ara wọn ni wọ́n fi ń
ṣe ìlù, tọkùnrin tobìnrin ni wọ́n ń ṣere apẹ́pẹ́.
Àwọn orin ayẹyẹ mìíràn ni ádàmọ̀ láàrin àwọn Ìjẹṣá (Àjàyí; 1975); àpàlá (Ọlábọ̀dé, 1974) orin
Àjàgbó ní ilẹ̀ Èkìtì (Olóyìnmínù, 1977) àti àwọn orin mìíràn bẹ́ẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá. Ó yẹ kí a mọ̀ pé
oríṣiríṣi ohùn ni wọ́n máa ń lò fún orin, èyí sì jẹ́ kí ó yátọ̀ sí ìsàré, bẹ́ẹ̀ náà sì ni a máa ń lu ìlú sí
orin kí ó baà́ lè ṣeé jó sí dáadáa.
i. Adedekún dekún
ii. Kọ́lá ńkọ́ o?
iii. Ọmọ mi Àjọkẹ́ torí rẹ mò ń ṣe ń ṣiṣẹ́, abbl
Ìsọ̀rí kẹrin ni orin erésụ̀pá. Díẹ̀ nínú àwọn orin tó ń jẹyọ lábẹ́ ìsọ̀rí yìí ni:
i. Bojú bojú o
ii. Ẹyẹ mélòó tolon̄ go wáyé?
iii. Ẹkùn mẹ́ran
iv. Mo pẹyẹkẹ́yẹ lókoò mi
A rí orin ìbílẹ̀ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí ilé ìṣúra tí àwọn Yorùbá kó oríṣiríṣi àṣà ìṣẹ̀m̀ báyé sí. Èyí kì í sìí jẹ́
kí wọn ó ṣìwàhù. Nínú orin, a máa ń rí oríṣiríṣi iṣẹ́ tí àwùjọ kan ń ṣe, irúfẹ́ oúnjẹ tí wón yàn
láàyò, èèwọ̀ wọn àti nǹkan mọ́nigbàgbé tó ti ṣẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a rí èèwọ̀ ìdílé kan nínú
Orin-Ọ̀sanyìn ní ìlú Oṣùn-ún Èkìtì:
Ọ́m’ẹṣọ Èrò
Ọ kún Mọdẹ̀ larìíjùri
Nínú orin òkè yìí la ti mọ̀ pé àwọn ìdílé yìí yóò máa rántí pé nǹkan àìgbọdọ̀jẹ ni ẹyẹ oriri. A tún
lè rí ìgbàgbọ́ àti èrò Yorùbá nínú orin ìbílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ orin ìbejì ìsàlẹ̀ yìí ṣe àfíhàn àṣà Yorùbá bí
wọ́n ṣe ní ìgbàgbọ́ pé wọ́n gbọdọ̀ máa se ẹ̀wà fún àwọn ìbejì lóòrèkóòrè:
Épo ń bẹ.
Ẹ̀wa ń bẹ ò.
Épo ń bẹ.
Ẹ̀wa ń bẹ ò.
Àyà mi ò já
Óó ye!
Àyà mi ò já láti bíbejì
Épo ń bẹ
Ẹ̀wa ń bẹ ò.
Ogunlọ́gọ̀ orin àbáláyé àwọn Yorùbá ló jẹ́ pé iṣẹ́ tí wọ́n ń rán sí àwùjọ ni pé àṣa ẹni kì í ṣe nǹkan
tí ẹ̀dá gbọdọ̀ gbàgbé.
Ọ̀kan lára isẹ́ tí Orin àbáláyé Yorùbá tún ń ṣe ni láti kìlọ̀ fún mútúnmúwá bí wọn ṣe gbọdọ̀ máa
hùwà ní àwùjọ. Àwọn ọ̀kọrin kì í fẹ́ kí àwọn ènìyàn àwùjọ ṣìwàhù. Wọ́n ka ẹ̀dá àwùjọ sí ọmọ
inú ọgbà tí kò gbọdọ̀ ṣi iṣu yọ. Wọn kì í sì í fẹ́ kí ẹ̀dá dáwọ́lé nǹkan tó lè pa wọ́n lára. Èyí ni a rí
nínú orin Etíyẹrí níbi tó ti ń forin rẹ̀ kìlọ̀ pé kí àwọn ọkùnrin ṣọ́ra fún ọmọbìnrin Ìbàdàn:
Etíyẹrí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn obìnrin tí ó ń sọ nípa ìwà ìbàjẹ́ wọn, kò lè ṣiṣẹ́ ilé kankan. Iṣẹ́ ilé sì ṣe
pàtàkì fún obìnrin. A mọ̀ pé orin yìí yóò jẹ́ kí ọkùnrin tó ń wá ìyàwó ronú rẹ̀ dáadáa kí o tó ṣe
nǹkan tí orin yìí ń kíyèsí. Gbogbo orin àbáláyé náà ló ń ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fún àwùjọ láti yàgò fún ìwà
tó lè kó bá ẹ̀dá, kí ayé bàá rójú, kí àwùjọ sì le tòrò bí omi-a-fòórọ̀-pọn. Nínú orin eréṣùpá ni a ti
rí bí wọ́n ṣe ń kìlọ̀ pé kò yẹ kí ẹ̀dá máa tàpá sí òfín èèwọ̀:
Mo pẹyẹkẹ́yẹ lókoò mi
Mo pàfèkafẹ̀ lókoò mi
Mo mú fún bàbá
Bàbá lá èé jẹ̀yí
Mo mú fún Ìyá
Ìyá lá èé jẹ̀yí
Mo mú fún Ọlọ́jà
Ọlọ́ja gbà á
Ó sọ ọ́ sẹ́nu káló
Ó dijọ́ keje
Wọ́n ránṣẹ́ wálé
Wón l’Ọ́lójà kú u…
Orin òkè yìí ń fí í yé wa pé ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan tẹ́nìkan kò ṣe rí, ojú rẹ̀ náà yóò rí nǹkan
tẹ́nìkan kò rí rí
Ipa kékeré kọ́ ni orin àbáláyé Yorùbá ń kó ní àwùjọ wọn. Orin tí àwọn ọ̀kọrin ń kọ fún àwọn tó
jẹ́ lóókọlóókọ láàrin ìlú máa ń fún àwọn ènìyàn ní ìṣírí láti gbé nǹkan ribiribi ṣe. Bí àwọn ọ̀kọrin
ṣe ń kọrin ki ọba, àti àwọn ìjòyè náà ni wọ́n ń kọrin ki àwọn tí ìwà wọn jẹ́ àwòkọ́ṣe láàrin ìlú.
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ‘yinniyinni kẹ́ni ó le ṣèmíìn. Àpẹẹrẹ irúfẹ́ orin yìí la rí nínú orin Etíyẹrí:
Àwọn ọmọdé pàápàá máa ń fún ara wọn ní ìṣírí láti ṣe eréṣùpá ìdárayá wọn. Irúfẹ́ orin ìṣírí bẹ́ẹ̀
ni
Ìyáàmi ‘ò le bẹ́
Bàbáà mi ‘ò le bẹ́
Emí nìkan mo le bẹ́
Pìììì
Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn nǹkan tí a ti mẹ́nu bà lókè yìí, orin àbáláyè Yorùbá tún wà fún ìdárayá.
Kò sí ẹni tí yóò máa kọrin tàbí fetísí orin tí ara rẹ̀ kò níí yá gágá. Orin a tilẹ̀ máa pa ìrònú rẹ̀. Tí
a bá wo orin Etíyẹrí tí wọ́n ń kọ ní alaalẹ́, a óò rí i wí pé gágá ni ara mùtúmùwà máa ń yá tí wọ́n
bá ń gbọ orin yìí. Ó tilẹ̀ hàn kedere nínú Orin-Ọ̀sanyìn pé a-máraya-gágá ni orin:
Ará yá
Ara yà
Ará yá’jọ́ àgbé o
Ará yá
Ara yà
Ará yá ‘jọ́ Ọ̀sanyìn
Ọ̀kan lára nǹkan tó mú àwùjọ Yorùbá dùn ni orin. Kò sí nǹkan tí àwọn ẹ̀yá yìí ń ṣe tí orin kì í kó
ipa pàtàkì níbẹ̀ láti fi adùn sí i. Orin aládùn tó ń jábọ́ lẹ́nu àwọn ọ̀kọrin fún onírúurú àṣeyẹ àti
ọdún ló ń jẹ́ kí àwùjọ Yorùbá jẹ́ à-rí-má-leè-lọ àti à-wò-padà-sẹ́yìn. Ó yẹ ká mọ̀ pé bí orin ṣe ń
múlùú dùn náà ló ń da ìlú rú. Ìwúlò orin àbáláyé pọ̀ yanturu tó fi jẹ́ pé a kò lè mẹ́nu bá wọ́n tán.
Kò sí orin tó jẹ́ pé kò ní iṣẹ́ kan pàtó tó ń ṣe fún àwùjọ tó wà.
Ìpín Kejì: Àkóónú Orin Àbàláyé Yorùbá
Oríṣìíríṣìí nǹkan ni a lè bá pàdé nínú orin àbáláyé Yorùbá. Àwọn ọ̀kọrin máa ń fí orin wọn sun
àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ ni, èyí sì ń jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe ohùn dídùn nìkan ni ó jẹni lógún nínú orin bí kì í
ṣe pé kí ọ̀kọrin sọ̀rọ̀, kó yọ kòmóòkun rẹ̀ jáde. Àwọn nǹkan tó sì ń jẹ jáde ní nǹkan-án ṣe pẹ̀lú
àṣà àwùjọ. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé ẹni tí yóò jẹ́ ọ̀kọrin àbáláyé gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tó dáńgájíá nínú àṣà
Yorùbá.
i. Ìbà
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí ewúrẹ́ òun àgùntàn wọlé lái kágò wọn yóò di ẹran-àmúso. Àwọn Yorùbá
ka ìbà jíjú sí púpọ̀. Kò sí nǹkan ti wọn yóò dáwọ́lé láìjúbà àwọn tó layé; ṣé àdáṣe níí hunni, ìbà
kò gbọdọ̀ hun ọmọ ènìyàn. Àwọn ọ̀kọrin máa ń sọ ọ́ di mímọ̀ pé níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé àwọn bá iṣẹ́
orin kíkọ lọ́wọ́ àwọn kan ni, ó yẹ kí àwọn fìbà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Nínú orin Ọ̀sanyìn, a bá
a pàdé báyìí:
Ọ̀rọ̀ í kẹ̀ gbọdọ̀ hun á
Gbogbo ara ẹdùn ni i l’agi
Àbọ̀bá lá a bí Jẹ̀gbẹ̀
Ulé ọkọ ni mi bi yè mi
Bíbá ni mi b’órò l’úlé ria
Bẹẹ̀ mi kẹ̀ m’ọni ẹ da ṣe
Tí a bá wo orin òkè yìí, a óò rí i pé ọkàn ọ̀kọrin yìí balẹ̀ pé kì í ṣe pé òun ṣe nǹkan láìgbàṣẹ lọ́wọ́
àwọn aṣaájú àti àwọn alayé. Bẹ́ẹ̀ náà la rí ìbà jíjú nínú orin agbè nínú Àlàbá (1985: 84):
ii. Oríkì
Àwọn ọ̀kọrin máa ń fẹ́ latí mọ oríkì ẹni tí ó pè wọ́n sóde eré tàbí ẹni tí àwọn gan-an bá pàdé lóde
eré tí wọ́n sì rò pé àwọn lè rí owó gbà lọ́wọ́ rẹ̀. Bí ọ̀kọrin bá ṣe lè ki oríṣìíríṣìí ìran tàbí orílẹ̀ sí ló
máa ń jẹ́ kí a mọ bóyá ó tó gban̄ gbaá sùn lọ́yẹ́. nínú oríkì ni ẹni tí ọ̀kọrin ń kì yóò ti mọ ibi tí òun
ti ṣàn wá térétéré bí omi ojú. Ọ̀kan lára oríkì ìdílé kan tó jẹyọ nínú orin Ọ̀sanyìn lọ báyìí:
iii. Àwàdà/Yẹ̀yẹ́
Àwọn ọ̀kọrin àbáláyé nífẹ̀ẹ́ láti máa pani lẹ́rìn-ín yálà láti má jẹ́ kí orin wọn súni tàbí láti fi irú
ọ̀rọ̀ àwàdà bẹ́ẹ̀ kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. A máa ń bá ọ̀rọ̀ àwàdà pàdé gan-an nínú orin Etíyẹrí:
Etíyẹrí fi àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú kan ṣe yẹ̀yẹ́ nínú orin rẹ̀ pé kò sí àǹfààní kan tí wọ́n lè ṣe ará ìlú:
iv. Èpè
Ní àwùjọ Yorùbá, wọ́n gbà pé èpè ni ẹ̀dá lè fi wẹ èpè. Àwọn ọ̀kọrin máa ń lo èpè láti dojú ìjà kọ
ọ̀tá ẹni tó ń náwó fún wọn. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé tí Ọ̀tá kò bá jẹ́ kí náwónáwó wọn ó rójú ráyè, owó
kò ní dápò ọ̀kọrin. Fún ìdí èyí, gbogbo nǹkan tó bá lè fa ìdíwọ́ fún olóore wọn ni wọ́n máa ń fi
èpè kojú rẹ́. Orin eégún ní ìlú Òkè Igbó la ti rí èyí:
Bẹ́ẹ̀ náà ni Etíyẹrí ń rọ̀jò èpè fún àwọn ọ̀tá Olóore rẹ̀:
Nínú orin-ìrẹmọlẹ́kún la ti rí bí àwọn Yorùbá ṣe ń gbé ọmọ gẹ̀gẹ̀ bí nǹkan tí kò-ṣeé-mọ́-nìí
láwùjọ àṣùwàdà ènìyàn:
Ìlẹ̀kẹ̀ lọmọ
Éé gbọdọ̀ já o
Ìlẹ̀kẹ̀ lọmọ éé gbọdọ já o
Akọ́bí ọmọ mi
Éé gbọdọ̀ kú rárá
Ìlẹ̀kẹ̀ lọmọ
Éé gbọdọ̀ já o.
Tí a bá wo orin àpàlà tí Àyìnlá Ọmọ Wúrà náà, a bá ọfọ̀ pàdé:
Gbogbo àwọn ọ̀kọrin àbáláyé ló ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àwíṣẹ tàbí nǹkan àmúṣagbára báyìí
láti sọ ara wọn di ẹni-tí apá ò leè ká tàbí kí ire lè máa wọlé fún wọn dáadáa.
Wọ́n ń fi orin yìí sọ fún àwùjọ pé ó yẹ kí mùtúmùwà yẹra fún owú-jíjẹ tí ó lè kó bá ìlọsíwájú.
viii. Ìbọ̀wọ̀fágbà
Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá ni pé àìfàgbà fẹ́nì kan ni kò jẹ́ káyé ó gún. Wọ́n sì máa ń sọ ọ́ pé ọmọdé
tó bá fẹ́ dàgbà kò ní gba ọ̀pá lọ́wọ́ àgbà. Èyí ni àwọn olórin àbáláyé sì máa ń gbé wọ inú orin
nípa bíbọ̀wọ̀ fún àwọn aṣáájú wọn. Nínú orin àpàlà tí Fàtáì Olówóńyọ̀ kọ, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ọmọ tó
bá bọlá fún àgbà náà yóò rí ọmọlẹ́yìn bọlá fún òun náà:
… Àwa tí júbà fárá iwájú,
Kọ́mọdé lè jubà fún wa.
Àwa ti júbà fárá iwájú
Kọ́mọdé lè jubà fún wa
Ọlátúnjí ìbà rẹ o …
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọ̀kọrin àbáláyé yòókù máa ń tẹnumọ èyí nínú orin wọn
5.0. Isọníṣókí
Àlàyépọ̀ rẹpẹtẹ̣ lórí orin ìbílẹ̀ Yorùbá. A sọ̀rọ lóri orin tó jẹmọ́ ayẹyẹ àti èyí tó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn. A
kò ṣàìmẹ́nuba àkóónú orin àti ìwúlò orin nínú ìdánilékọ̀ọ́ yìí.
1.0. Ìfààrà
Erémọdé tàbí eréṣùpá kún fún oríṣiríṣi ewì, ọ̀rọ̀-geere àti ewì tí àwọn Yorùbá fi ń dáni lára yá,
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ náà. Àwọn tí àlàyé yóò wáyé lórí wọn ni:
Àlọ́-onítàn (àlọ́-àpagbè)
Àlọ́-àpamọ̀
Orin àlọ́ (orin-eréṣùpá)
Àrọ̀, abbl.
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
Àlọ́-onítàn (àlọ́-àpagbè)
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ fèyíkọ́gbọ́n alálọ̀ọ́, àlọ́-onitàn ló máa ń wá sọ́kàn ẹni. Àwọn àdúgbò kan nílẹ̀
Yorùbá kì í pè é ní àlọ́, ìtàn ni wọ́n ń pè é, àlọ́ àpamọ̀ nìkan ni wón mọ̀ sí àlọ́. Àlọ́ yìí kan náà ni
àwọn Kàbà tó jẹ́ Owé-Yorùbá ń pè ní arọ́, yálà ó ní orin tàbí kò ní. Ní agbègbè Ìjẹ̀bú, pẹ́rọ̀ọ́ ni
wọ́n ń pe àlọ́-onítàn tí kò bá ní orin. Ní ayé àtijọ́, alẹ́ nígbà tí wọ́n bá jẹun tán ni wọ́n ń pa àlọ́ tí
ó jẹ́ ọ̀kan lára eré-òṣùpá. Ọ̀làjú àti ẹ̀kọ́ ìgbàlódè ti jẹ́ kí àlọ́ máa wáyé ní ojúmọmọ. Ìdí tó fi rí
bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n máa ń lo àlọ́ láti fi kọ́ ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé. Kì í ṣe pé bóyá èèwọ̀ ni láti pàlọ́
lọ́sàn-án, wọ́n kàn ń fi í dẹ́rù ba ọmọdé ni kí ó bàá lè fọkàn sí iṣẹ́ tó ń ṣe láàárọ̀ àti ní ọ̀sán. Ní alẹ́
nígbà tó jẹ́ pé gbogbo ẹ̀dá yóò máa sinmi iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe ní ojúmọmọ, wọn yóò lo àlọ́ láti fi
gbádùn, láti fi í pa ìrònú rẹ́ àti láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. A lè pín fèyíkọ́gbọ́n alálọ̀ọ́ sọ́nà méjì:
i. Àlọ́-oníjàpá
ii. Àlọ́-kòníjàpá
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, ọ̀rọ̀ gbogbo kì í sé lórí alábahun. A fẹ́rẹ̀ẹ́ lè sọ pé ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún
àlọ́ onítàn Yorùbá ló dálé ‘ìjàpá’.
Àlọ́-àpamọ̀
Àlọ́-àpamọ̀ jẹ́ erémọdé tí àwọn Yorùbá máa ń lò láti jẹ́ kí ọmọdé ní agbára tàbí ẹ̀bùn ìyára sí ọ̀rọ̀
tó bá ta kókó. Kí àlọ́-onítàn tó wáyé ni wọn yóò ti pa àlọ́-àpagbè. Ẹ jẹ́ kí a wo àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ yìí:
i. Apàlọ́: Ààlọ́ o
Olùgbọ́: Ààlọ̀
Apàlọ́: Kí ló ń lọ lójúde Ọba tí kò kí Ọba?
Olùgbọ́: èmí mọ̀ ọ́n o
Apàlọ́: Kín ni o?
Olùgbọ́: Àgbàrá òjò ni
Àrọ̀
Àrọ̀ náà jẹ́ ọ̀kan nínú ìtàn fèyíkọ́gbọ́n tí àwọn Yorùbá fi ń kọ́ni lẹ́kọ́ọ̀. Ó jẹ́ okun àti agbára fún
ẹ̀dà láti lè ronú jinlẹ̀ ní kíákíá lórí ọ̀nà tí a lè gbà láti yanjú ìṣòro tàbí àwọn nǹkan tó bá ta kókó.
Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé ẹni tó lè wá ìdáhùn sí ìbéèrè tó ń jẹyọ nínú àrọ̀ kíákíá, kò lè ní ìṣòro láti ṣe
àṣeyọrí tàbí kojú làásìgbò ayé. Abímbọ́lá (1975: 396 – 387) fún wa ní àpẹẹrẹ irúfẹ́ àrọ̀ yìí, tí
àwọn Yorùbá máa ń gbé fáyé rí ní ìlànà ewì àti ọ̀rọ̀-geere. Asọ̀tàn yóò gbé ìbéèrè tàbí àlàyé tó
kún fún ìtàn sí iwájú òǹgbọ́tàn ní ìrètí pé wọn yóò ní làákàyé láti lè so ìbéèrè náà mọ́ nǹkankan
nínú ìdáhùn wọn. Oríṣìí àrọ́ méji tó wà ni:
i. Àrọ̀ àpamọ̀
ii. Àrọ̀ onítàn
Àrọ̀ àpamọ̀ máa ń farajọ àlọ́ àpamọ́, ìyàtọ̀ tó wá láàrin àlọ́ àpamọ̀ àti àrọ̀ àpamọ̀ ni pé ẹni tó ń járọ̀
àpamọ̀ yóò ṣàlàyé ní kíkún ni, kì í ṣe pé á kàn mú ìdáhún wá ṣákálá láìṣe àlàyé ìdí tí nǹkan náà fi
rí bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ nínú àlọ́ àpamọ̀.àpẹẹrẹ àlàyé yìí dà?
Orin Eréṣùpá
Orin eréṣùpá ni àwọn orin tí àwọn ọmọdé máa ńkọ nígbà tí wọ́n bá ńṣe eré òṣùpá. Oríṣiríṣi orin
ló jẹmọ́ eréṣùpá. Irúfẹ́ àwọn orin wọ̀nyí sì máa ń mú orí ọmọdé yá gágá, ó sì ń mú inú wọn dùn
pẹ̀lú. A lè bá irúfẹ́ àwọn orin wọ̀nyí pàdé:
i. Mo pẹyẹkẹ́ye lóko mi
ii. Ẹyẹ mélòó tolongo wáyé
iii. Kí ló ń lẹ́jẹ̀
iv. Àdùkẹ́ làwa ń bá ṣeré, abbl.
5.0. Ìsọníṣókí
A ṣàlàyé nǹkan tí erémọdé jẹ́ láwùjọ Yorùbá. A tẹ̀síwájú nípa ṣíṣàlàyé orin eréṣùpá, àlọ́-
onítàn (àlọ́-àpagbè) àrọ̀ àti orin inú àlọ́. Ìgbà tí erémọdé ń wáyé àti àwọn tó ń ṣe é kò ṣàì
wáyé nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí.
7.0.Ìwé Ìtọ́kasí
Orímóògùnjẹ́, O. (1996), Lítíréṣọ̀ Alohùn Yorùbá, Lagos: Káróhunwí Publishers.
Babalọlá, A. 1979), Àkójọpọ̀ àlọ́ Ìjàpá, Apá Kejì Ìbàdàn: University Press Ltd.
5. Módù Karùn-ún
Ẹ̀kọ́-ilé
1.0. Ìfáàrà
Ẹ̀kọ́-ilé ṣe pàtàkì láwùjọ Yorùbá. Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá ni pé ọmọ tí wọn kò kọ́ ni yóò gbé ilé tí
wọ́n kọ́ tà. Ìdí rèé tí wọ́n fi ń sọ pé ó pọn dandan kí òbí má máa lé owó nìkan bí kò ṣe pé kí wọ́n
ṣe ojúṣe wọn lórí ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn.
4.0. Ì̀dánilẹ́kòọ́
Láti kékeré ni Ìmọ̀le ti ń kọ́mọ rẹ ḷẹ́sìn. Áti inú oyún ni Yorùbá mọ̀ pé ó yẹ kí òbí ti máa kọ́
ọmọ wọn. Ẹ jẹ́ kí a ṣàlàye àwọn ìgbésẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí:
i. Ẹ̀kọ́ àbínimọ́
ii. Ẹ̀kọ́ ìṣirò
iii. Ẹ̀kọ́ erémọdé
i. Ẹ̀kọ́ àbínimọ́
Láti inú oyún ni àwọn Yorùbá ti gbà pé òbí ti gbọdọ̀ máa kọ́ ọmọ wọn. Tí ọmọ bá yí ara ní
ìyíkúyìí nínú, aboyún yóò fi ìka ta ọ̀gangan ibẹ̀ láti lè jẹ́ kí oyún náà mọ̀ pé kò yẹ kí ènìyàn ni
ẹ̀dá kejì lára. Ẹ̀kọ́ àbínimọ́ yìí náà ló dórí kíkọ́ ọmọ bó ṣe lè sọ̀rọ̀. Ọmọ yóò máa wo àwọn
àgbà iwájú rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, á máa gbìyànjú láti sín wọn jẹ títí yóò fi lè máa sọ̀rọ̀ dáadáa.
Wọn kò ní sọ̀rọ̀ àlùfàńsà lójú rẹ̀ kí ó má bàá di onísọkúsọ.
Ení bí ení
Lọmọdé ń kawó.
Èjì bí èjì
Làgbà ń tayò.
Ẹ̀ta bí ẹ̀ta
Ẹ jẹ́ ká tara wa lọ́rẹ.
Ẹ̀rin bí ẹ̀rin
Ẹní rínni là á rín
Àrún bí...?
Ẹ̀fà bí ẹ̀fà
Ẹ jẹ́ ká fara wa mọ́ra.
Ẹ̀jọ bí ẹ̀jọ
Ẹní bíni làá jọ.
Ẹ̀sán bí ẹ̀sán
Ọba jálẹ́ ó san wá.
Ẹ̀wá bí ẹ̀wá
Ọba má wáhàlá wa.
Tí ọmọdé bá mọ orin yìí dáadáa, yóò ràn án lọ́wọ́ láti mọ ìṣirò àti òǹkà Yorùbá dáadáa.
iii. Ẹ̀kọ́ erémọdé: ni oríṣiríṣi àwọn erémọdé bi àlọ́-àpamọ̀, àlọ̀-onítàn àti àrọ̀ ti wọ́n máa fi ń
dárayá.
5.0. Ìsọníṣókí
Ìran Yorùbá ka ẹkọ́-ilé sí kòṣeémánì-ín. Oríṣiríṣi ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń tẹ̀lé láti kọ́ ọmọ la gbé yẹ̀wò
nú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí. Ẹ̀kọ́-ilé máa ń jẹ́ kí ọmọ mọ àṣà dáadáa, kí ó sì tún mọ ìwà á hù.
1.0. Ìfaara
Yorùbá bọ̀, wọ́n ní ‘àwáyéèkú kan kò sí, ọ̀run nìkan làrèmọ́bọ̀; kò sẹ́ni tí kò níí kú, tóko baba rẹ̀
kò níí dìgbòrò’. Wọ́n gbà pé pé ikú ń sa ẹni tí kò tíì kú lẹ́gbẹ bí iṣu ni. A tún gbọ́. wọ́n fi ikú wé
asúnmúsí tó ń fi ikun pamọ́, nítorí pé bí kò wá níkun, yóò wá ní kẹ̀lẹ̀bẹ̀. Yorùbá kì í banújẹ́ lórí
ikú, àfi tó bá jẹ́ pé ọmọdé tàbí ọ̀dọ́ ló kú. Òkú ẹ̀kọ, ìdùnnú àti ayẹyẹ ni wọ́n ka òkú àgbà sí. Ìdí
rèé tí a fi ń gbọ́ ọ lẹ́nu apohùn níbi òkú-pípè pé:
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
Oríṣiríṣi ikú ló ń pa ẹ̀dá, èyí ló sì fi jẹ́ pé oríṣìí ètò ìsìnkú ló wà ní àwùjọ Yorùbá. Ẹ jẹ́ ká wo
oríṣìí ikú tó wà:
Òkú àgbà
Òkú ọmọdé
Òkú ọ̀dọ́
Òkú abínúkú /apokùnso
Òkú ẹni tí Òrìṣà/Ìbọ pa
Òkú aboyún
Òkú adẹ́tẹ̀
Òkú abuké
Òkú Ọba
Òkú Ọdẹ
Òkú awo, abbl.
Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yií, a óò ṣàlàyé àwọn òkú yìí lọ́kọ̀ọ̀kan, kí a lè mọ ìyàtọ̀ tó wà láàrin wọn
láwùjọ Yorùbá
i. Òkú Àgbà
Tí arúgbó kan bá ti papòdà, ni àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ti fi í to aládùúgbò àti ará ìlú létí pé àgbà kan
ti gbésẹ̀ nínú ẹbí wọn. Bí wọ́n ṣe ń túfọ̀ òkú àgbà máa ń yàtọ̀ ládùúgbò kan sí òmíràn nílẹ̀
Yorùbá. Níbò mìíràn, ìbọn ni wọ́n fi máa ń túfọ̀, kò sì rí bẹ́ẹ̀ níbòmìíràn. Láyé àtijọ́, wọ́n lè sin
òkú lọ́jọ́ tó kú tàbí lọ́jọ́ kejì sí ̀ìkẹta. Lẹ́yìn tí wọ́n bá sin òkú tán, wọn yoò ṣe ìta àti ìje (ọjọ́ kẹta
àti keje). Àṣekágbá òkú tàbí àsinparí òkú náà tún wà tí wọn yóò dáná rẹpẹtẹ fún gbogbo ara ìlú.
v. Òkú Aboyún
Tí aboyún bá kú, àwọn Olórò ló ń sin ín pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètùtù. Wọn yóò fi ọ̀bẹ la inú rẹ̀ láti gbé ọ̀lẹ̀
(ọmọ) inú rẹ̀ jade. Wọn yóò sin wọ́n lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ kí aburú bẹ́ẹ̀ má bàá ṣẹlẹ̀ mọ́.
5.0. Ìsọníṣókí
Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, a rí i pé ìran Yorùbá kò rí ikú gẹ́gẹ́ bí òpin ẹ̀dá. Oríṣiríṣi ikú ló ń pa ẹ̀dá, ó sì
ní bí wọ́n ṣe ń sin òkú kọ̀ọ̀kan nílẹ̀ Yorùbá. A rí i pé kò sí ayẹyẹ ìsìnkú fún òkú ọmọdé àti òkú
ọ̀dọ́, àfi àgbà nìkan ni wọ́n ti lè file pọntí fọ̀nà rokà.
7. 0. Ìwé Ìtọ́kasí
Ògúnbọ̀wálé, P. (1966), Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá, Ìbàdàn: Oxford University Press.
Adéoyè, C. (1985) Ìgbàgbọ́ àti Ẹ̀sìn Yorùbá, Ìbàdàn: Evans Brothers Ltd.
7. Módù Keje
Ìgbéyàwó
1.0. ÌfááràTọ́mọ bá tóó lọ́kọ́, wọ́n á fún un lọ́kọ́. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó rí láwùjọ Yorùbá. Tí
ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin bá ti dàgbà dáàyè kan, dandan ni kí àwọn òbí rẹ̀ máa ronú bí yóò
ṣe lọ́kọ tàbí ní ìyàwó. Nílẹ̀ Yorùbá, ọkùnrin ló máa ń ṣètò láti ní ẹbí. Nǹkan tí a ní lọ́kàn ni
pé ọkùnrin ló ń wá ìyàwó, kì í ṣe obìnrin ló ń wá ọkọ.
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
Èto ìgbéyàwó ní ìgbésẹ̀ tó mọ́yán lórí, ó sì wà ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé bó ṣe hànde nísàlẹ̀ yìí:
Ìfojúsóde
Alárinà
Ìdẹ̀giri
Ìjọ́hẹ̀n
Ìtọrọ-ọmọ
Ìdána
Ayẹyẹ ìgbéyàwó
Ọmọkùnrin tí kò tíì ní ìyàwó ni wọ́n ń pè ní àpọ́n. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àwàdà, oríṣi àpọ́n méta ló wà.
Èkínní ni àpọ́n mo ń wòye (ọmọkùnrin tó wóbìnrin tó wù ú), èkejì ni àpọ́n mo róye (ọmọkùnrin
tó rẹ́ni tó wù ú) àti àpọ́n ṣa-n-ko (ọmọkùnrin tí kò ní ìyàwó, tí kò sì ní in lọ́kàn láti ní).
Ọmọkùnrin yóò máa wá obìnrin tó lè fẹ́ títí tí yóò fi rẹ́nìkan. Tó bá ti rẹ́ni tí ó wù ú, yóò wá
ẹnìkan tí yóò jẹ́ alárinà. Alárinà ni ọmọkùnrin yóò máa rán sí ọmọbìnrin, tí yóò sì máa fún
ọkùnrin lésì títí tí àwọn méjèèjì yóò fi fojú kanra. Iṣẹ́ alárinà ti kásẹ̀ nílẹ̀ nìyẹn, ìdí rèé tí wọ́n fi ń
sọ pé bí aya bá ti mojú ọkọ tán, alárinà a yẹ̀ba.
Ìgbésẹ̀ tó kàn ni kí àfẹ́sọ́nà méjèèjì máa ríra déédé lẹ́sẹ̀ kùkú tàbí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. Èyí ló jẹ́ kí
ọmọbìnrin máa gba owó ìdẹ̀giri lẹ́yìn tó bá ti gbà pé òun yóò ṣaya ọmọkùnrin náà. Lẹ́yìn ọjọ́ tàbí
oṣù díẹ̀, tí obìnrin bá ti gbà láti fẹ́ ọkùnrin, Iṣẹ́ ọmọkùnrin ni láti fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn òbí rẹ̀ létí.
Àwọn òbí yóò bẹ̀rẹ̀ ìwádìí wọn lórí ẹbí ọmọbìnrin náà láti lè mọ bí wọ́n ṣe rí; bóyá wọ́n ṣeé fẹ́
nípa pé wọn kì í ṣe onígbèsè, wọn kò ní àrùn ìdílé bíi aágànnà/wèrè, wárápá abbl. Tí ìwádìí wọn
bá dópin tí wọ́n rí i pé ẹbí tó dára ni, ìgbésẹ̀ tó kàn ni kí wọn lọ tọrọ ọmọ.
Bàbá ọmọkùnrin náà yóò fi ọ̀rọ̀ náà lọ àgbà agboolé tí yóò mú àgbà díẹ̀ lọ́wọ́ lọ sílé ọmọbìnrin
láti rí àwọn òbí rẹ̀ fún ìtọrọ-ọmọ. Tí òbí ọmọbìnrin bá ti gbà, kí wọn dájọ́ ìdána ló kù. Lọ́jọ́ ìdána,
àwọn ará ilé ọkọ yóò kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wá ilé àna wọn. Lára nǹkan tí wọ́n ń kó lọ ilé àna ni:
iṣu,
obì,
àádùn,
ìrèké,
ògidì ẹmu,
epo pupa,
ẹja,
ewúrẹ́, abbl.
Lẹ́yìn ìdána, ayẹyẹ ìgbéyàwó ló kàn. Akutupu máa ń hu lọ́jọ́ ayẹyẹ ìgbéyàwó. Wọ́n máa ń file
pọn ọtí, fọ̀nà rokà, fi gbogbo agbada dínran. Wọ́n a pe onílù àti olórin. Gbogbo rẹ̀ yóò máa dùn
yùngbà. Tí ìyàwó bá ń bọ̀ nílé ọkọ, kò gbọdọ̀ bá ọkọ rẹ̀ nílé. Ìyàwó yóò wọlé tán kí ọkọ rẹ̀ tó wá
bá a nílé. Alẹ́ ọjọ́ náà ni yóò jẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ojúṣe lọ́kọláya yóò wáyé láàrin àwọn méjèèjì. Tí ó bá
jẹ́ pé ọmọbìnrin náà kò tíì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí, àwọn ilé ọkọ yóò gbé ẹ̀kún agbè ẹmu gẹ́gẹ́
bí ọrẹ fún àwọn àna wọn, ṣugbọ́n tí ó bá jẹ́ pé ó ti ń bá ọkùnrin ṣe pọ̀, ààbọ̀ agbè ẹmu àti èédú ni
wọn yóò gbé fún àwọn àna wọn. Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ní ẹ̀tọ́ láti máa gbé pọ̀ gẹ́gẹ bí tọkọtaya.
5.0. Ìsọníṣókí
Láwùjọ Yorùbá, àìlóbìrin kò ṣeé dákẹ́, gbogbo ayé níí báni dá sí i. Ọmọkùnrin tó bá ti tóó láya
yóò fojú síta, yóò sì wá alárinà tó bá ti rí ọmọbìnrin tó wù ú. Àwọn òbí rẹ̀ yó lọ tọ̣rọ ọmọbìnrin
náà lẹ́yìn ìwádìí lórí ẹbí ọmọbìnrin. Ètò ayẹyẹ ìgbéyàwó yóò wáyé lẹ́yìn ìdána.
1.0 Ìfáàrà
Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, èniyàn ni orúkọ tí gbogbo ọmọ adáríhurun ń jẹ́. Kò sí orúkọ kan tó yà wọ́n
sọ́tọ̀. Ọ̀rúnmìlà ló pa á láṣẹ pé ẹnikọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ ní orúkọ tire. Bí ẹnikọ̀ọ̀kan ṣe ń ní orúkọ tirẹ̀
títí dòní rèé. Ìsọ̀rí bí mẹ́ta ni a lè pín orúkọ sí, àwọn náà ni orúkọ àbísọ, orúkọ àmútọ̀runwá
àti oríkì. Láyé àtijọ́, ọjọ́ keje ni wọ́n ń sọ ọmọbìnrin lórúkọ, ọjọ́ kẹsàn-án ni ti ọmọkùnrin, tí
ọjọ́ kẹjọ sì jẹ́ ti àwọn ìbejì. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ láyé òde-òní, ọjọ́ kẹjọ ni gbogbo ọmọ.
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
Ní ọjọ́ ìsọmọlórúkọ, ọ̀pọ̀ èròjà tẹ́nu ń jẹ ní wọn yóò kó sílẹ̀ láti wúre fún ọmọ tuntun. Lára àwọn
èròjà náà ni:
Ìrèké
Ataare
Àádùn
Omi
Iyọ̀
Ọ̀bẹ
Oyin
Orógbó
Epo
Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn èròjà wọ̀nyí ló ní àrokò tí wọ́n fi ń pa fún ìgbé-ayé ọmọ tuntun náà.
i. Ìrèké
Àrokò tí ìrèké ń pa ni pé ayé ọmọ náà yóò dùn bí irèké. Bí iná ṣe ń bọ̀wọ̀ fún ìrèké ní àwọn ẹni
ibi yóò máa bọ̀wọ̀ fún ọmọ náà.
ii. Àádùn
Kí ayé ọmọ náà dùn bí àádùn
iii. Omi
Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé omi kì í balẹ kó má nípa, kí ọmọ náà nípa sí owó, ọmọ, aya, ọrọ̀, ipò, abbl.
Omi ló ń poró iná, kí ọmọ ṣẹ́gun ọ̀tá, kó rẹ́yìn odi.
iv. Ẹja: Tútù ni a máa ń bá ilé ẹja, ilé ẹja kì í gbóná; àdúrà tí à ń fi èyí gbà fún ọmọ ni pé
ayé rẹ̀ yóò tutù àti pé kò ní rí ìdààmú nílé ayé rẹ̀. A máa ń fi ẹja gbígbẹ ṣe àdúrà pé orí
ni ẹja fi ń la ibú, ọmọ náà yóò fi orí rẹ̀ la gbogbo ìsòro ayé rẹ̀ já yóò sì borí gbogbo
wọn.
v. Iyọ̀: Dandan ni iyọ̀ jẹ́ ní àwùjọ oúnjẹ, a sì máa mú oúnjẹ dùn. Yàtọ̀ sí èyí, iyọ̀ kì í jẹ́ kí
nǹkan tètè díbàjẹ́. Àdúrà tí à ń fi iyọ̀ gbà fún ọmọ tuntun ẹ̀jẹ̀ ọ̀run ni pé iyọ̀ àti adùn
ayé ni yóò jẹ́. Yàtọ̀ fún èyí, bí iyọ̀ ṣe máa ń jẹ́ kí nǹkan tọ́jọ́, béẹ̀ ni òun náà yóò tọ́jọ́,
kò sì ní díbàjẹ́ pẹ̀lú.
vi. Orógbó
Orógbó níí gbó wọn sáyé. Kí ọmọ náà gbó, kí ó tọ́, kó má kú ní rèwerèwe.
vii. Epo pupa: Àdúrà tí à ń fi epo pupa ṣe ni pé kí ọmọ tuntun náà fi ìrọ̀rùn, ìdẹ̀ra àti ìtura
gbé ilé ayé rẹ̀. A tún ń gbà á ní àdúrà pé ọmọ náà kò ní rí ìpọ́njú láyé.
viii. Atare: Àdúrà ìsọdipúpọ̀ ni a máa ń fi ataare ṣe pé ọmọ náà yóò dirún yóò sì digba.
Yóò lówó lọ́wọ́, yóò bímọlémọ, yóò sì pọ̀ ní ọrọ̀. A tún ń fi ataare ṣe àdúrà ìṣọ̀kan pé
bí ọmọ ataare ṣe dì papọ̀ sójú kan ní odidi náà ni ọmọ yìí yóò dúró fún ìsọ̀kan yóò sì
jẹ́ okùnfà ìṣọ̀kan láàrin ìdílé rẹ̀.
ix. Ọtí ṣe pàtàkì púpọ̀ láwùjọ. Yorùbá á ní ‘ẹni ọtí kì í tí’. Àdúrà tí à ń fi ọtí ṣe fún ọmọ
tuntun ni pé ayé rẹ̀ kò níí tí bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní tẹ́ láwùjọ pẹ̀lú.
x. Obì: Yorùbá gbà pé obì níí bi ikú àti àrùn dànù, nítorí èyí wọn a máa fi obì wúre fún
ìkókó pé obì yóò bi ikú àti àrùn dànù nílé ayé rẹ̀.
Láyé àtijọ́, wọ́n tún máa ń ṣe ẹsẹ̀ǹtayé ọmọ kí wọn lè mọ bí ìrìnàjò rẹ̀ yóò ṣe rí láyé. Èyí ni yóò jẹ́
bí atọ́nà fún ọmọ náà nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ̀ lode ayé. Wọn yóò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì tẹlẹ̀ kí ó má
bàá ṣìrìn, kí ó má bàá ṣìṣe.
5.0. Ìsọníṣókí
Oríṣìí ìsọ̀rí mẹ́ta ni orúkọ Yorùbá pín sí: oríkì, àbísọ àti àmútọ̀runwá. Ìyàtọ̀ díẹ̀ ti wà nínú
ìsọmọlórúkọ ayé àtijọ́ sí tòde-òní. Àrokò ni àwọn èròjà tí wọ́n fi ń sọmọ lórúkọ ń pa sí àwùjọ.
1.0. Ìfáàrà
Lára ètò ìṣèlú àbáláyé ni oyè-jíjẹ wà láwùjọ Yorùbá láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, oyè-jíjẹ
bẹ̀rẹ̀ láti orí olórí ẹbí, tàbí, tí a tún lè pè ní Mọ́gàjí níbòmìíràn, tó fi dórí Baálẹ̀, Ìjòyè àti Ọba ìlú.
Láyé àtijọ́, kí wọn tó fi ẹnikẹ́ni joyè tàbí sí ipò aláṣẹ, wọn yóò bi ifá léèrè kí wọn baà lè mú ẹni tí
yóò ṣe ìlú lóore. Èyí tó pọn dandan lóde-òní ni láti béèrè lọ́wọ́ Ifá kí wọn tó yan Ọba.
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
Ní ìbẹ̀rẹ̀, àwọn Ọba, Ìjòyè, Baálẹ̀ àti Baálé ló ń ṣèlú kí àwọn Aláwọ̀ funfun tó dé sí àwùjọ
Yorùbá. Oníkálukú wọn ló ní ojúṣe tirẹ̀ láàrin ìlú títí tó fi dé agboolé. Àlàyé yóò wáyé lórí
ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ipò aláṣẹ wọ̀nyí ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé.
i. Baálé
Olórí agboolé ni Baálé jẹ́. Oníwà tútù, tí ó lọ́gbọ́n òun làákàyè, tó sì kóni mọ́ra ni wọ́n máa ń fi jẹ
Baálé láwùjọ Yorùbá. Iṣẹ́ Baálé ni láti mójú tó gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ agboolé. Ó gbọdọ̀ gbọ́n nínú àti
lẹ́yìn, láti lè parí aáwọ̀ láàrin àwọn ọmọ-ilé láìfi igbá kan bọ̀kan nínú. Ẹjọ́ tó bá ju agbára rẹ̀ lọ ni
yóò taari sọ́dọ̀ Baálẹ̀ láti yanjú láìṣègbè lẹ́yìn ẹnikẹ́ni. Tí oyè bá tọ́ sí agboolé kan, Baálé ni àwọn
aláṣẹ yòókù yóò ránṣẹ́ sí láti fa ọmọ oyè kalẹ. Lákòótan, Baálé gbọdọ̀ rí i pe gbọ́nmi-sí-i-omi-ò-
tó kò sí ní agboolé.
ii. Baalẹ̀
Baálẹ̀ ni olórí tàbí aláṣẹ ìletò/ìgbèríko kan ní àwùjọ Yorùbá. Ẹni tó lọ́gbọ́n lórí láti darí àwọn
ènìyà ni wọ́n ń fi jẹ Baálẹ̀. Láyé àtijọ́, Baálẹ̀ ló máa ń jábọ̀ bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ ní ìgbèríko
fún Ọba. Òun náà ló máa ń ṣètò ìṣákọ́lẹ̀ fún Ọba. Àwọn ìlú amọ́nà ló ṣábà máa ń ní Baálẹ̀ láyé
àtijọ́. Ọ̀rọ̀ tàbí awuyewuye tí ó bá ju agbára rẹ̀ lọ ni yóò gbé lọ síwájú Kábíyèsí.
iii. Ọba
Láti ìgbà láéláé ni Oba ti máa ń jẹ́ olórí ìlú. Wọn kì í fi ènìyàn yẹpẹrẹ jọba ìlú. Ẹni tó ní làákàyè
tó sì lè ṣe àkóso ìlú ni wọ́n ń yàn ní Ọba nílẹ̀ Yorùbá. Òfin wà pé ẹni tí wọ́n fẹ́ fi jọba kò gbọdọ̀
ní àlébù bí àìsàn ara tàbí kó jẹ́ ẹni-Òòṣà bí aràrá, abuké, arọ, abbl. Ètò tó nípọn wà fún Ọba-jíjẹ, ó
sì ní ìgbésẹ̀ tí wọ́n máa ń tẹ̀lé kí ó bàá lè rí bó ṣe yẹ kó rí. Àwọn Afọbajẹ gbọdọ̀ béèrè lọ́wọ́ Ifá tó
jẹ́ ẹlẹ́rìí-ìpín kí ó tọ́ wọn sọ́nà kí àṣìmú má bàá wáyé. Tí Ifá bá ti júwe ẹni tí Ọba tọ́ sí, kí ìmúra
ìfọbajẹ bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu ló kù. Ọba gbọdọ̀ wà ní ìpẹ̀bí fún àsìkò kan kí ìwúyè tó lè wáyé. Iye ọjọ́ ti
Ọba gbodọ̀ wà ní ìpẹ̀bí lè yàtọ̀ láti ìlú kan sí ìkejì. Lẹ́yìn ìpẹ̀bí, ayẹyẹ ìwúyè yóò wáyé pẹ̀lú
tìlùtìfọn.
5.0. Ìsọníṣókí
Bí ìṣàkóso láti orí baálé títí tó fi dórí ọba ṣe rí láyé àtijọ́ ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ kó yéni. Àlàyé mìíràn ni
bí wọ́n ṣe ń joyè kọ̀ọ̀kan àti bí ayẹyẹ ìwúyè ṣe ń wáyé láwùjọ Yorùbá. Ó di mímọ̀ pé Ifá ni wọ́n fi
ń tọsẹ̀ ẹni tí yóò joyè láwùjọ Yorùbá.
1.0. Ìfáárà
Iṣẹ́ ìbílẹ̀ Yorùbá ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti iṣẹ́ aró-dídá. Ọkùnrin ni a mọ̀ mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ tó sì jẹ́ pé
obìnrin ló jẹ́ gbajúgbajà nidìí aró-dídá. Oríṣiríṣi ọ̀nà ní iṣẹ́ àgbẹ̀ pín sí, Nǹkan tó jẹ mọ́
ọ̀gbìn ni a lè pè ní iṣẹ́ àgbẹ̀ láwùjọ Yorùbá láyé àtijọ́. Oríṣiríṣi irinṣẹ́ ló rọ̀ mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀,
bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún aró-dídá. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí yóò tú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn palẹ̀ kí a fi le mọ bí ìran
Yorùbá ṣe kááràmásìkí wọn sí.
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
i. Iṣẹ́ Àgbẹ̀
Iṣẹ́ tó gbajúgbajà tó tún lókìkí ni àgbẹ̀ jẹ́ láwùjọ Yorùbá. Tọkùnrin tobìnrin ló le jẹ́ àgbẹ̀, ó kàn jẹ́
pé ọkùnrin ló pọ̀ jù nínú rẹ̀ ni. Yípo ọdún ni wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, ìbáà jẹ́ ìgbà òjò, ẹ̀ẹ̀rùn tàbí
ìgbà ọyẹ́, Kò sí ìgbà tí iṣẹ́ yìí kò lè wáyé, ó wà lọ́wọ́ nńkan tí wọ́n bá fẹ́ ṣe. Oríṣiríṣi iṣẹ́ àgbẹ̀ ló
wà:
Iṣẹ́ àgbẹ̀ aládàá-ńlá ni àwọn àgbẹ̀ oníkòkó, olóbì, oníkọfí, onírọ́bà, ẹlẹ́pà, olóko-àgbàdo-ńlá,
onírẹsì, abbl. Lẹ́yin odún mẹ́rin sí márùn-ún ni àgbẹ̀ oníkòkó yóò to lè máa kórè nǹkan ọ̀gbìn
rẹ̀.Ìtọ́jú tó péye sì gbọdọ̀ wà fún kòkó kí fárífárí má bàá pa á, kí ó má bàá rì, àti kí àfomọ́ má bàá
pa á. Wọn gbọdọ̀ máa roko sí i déédé kí igbó má bàá kún bò ó. Wọn gbọdọ̀ máa fin in ní oògùn
nígbà òjò kí èso kòkó má bàá rì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbọdọ̀ máa gé àfòmọ́ orí kòkó kí ó má bàá pa á lára.
Tí èso kòkó bá pọ́n ni wọn yóò ká a, wọn yóò pa á láti yọ ọmọ (kóró) inú rẹ̀ jade. Lẹ́yìn èyí ni
wọn yóò bà á fún ọjọ́ mẹ́ta kí wó́n tó sa á fún bí ọ̀sẹ̀ kan àti ààbọ̀ kí wọn tó lọ tà á. Obì nítirẹ̀, kí
wọ́n roko sí i fún bí ọdún márùn-ún sí mẹ́fa kó tó bẹ̀rẹ̀ síí so. Ọjọ́ tí wọ́n bá ká obì náà ni wọn
yóò yọ ọ́ nínú apópó rẹ̀ ti wọn yóò sì tà á. Wàhálà obì kò pọ̀ bí ti kòkó. Àrojẹ kì í ṣe oko dídá
rẹpẹtẹ. Nǹkan jíjẹ bí iṣu, kókò, gbáàgúdá, erèé, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àti nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ló wà fún. Oko etílé ni
ti àgbẹ̀ àbọ̀ṣẹ́, nígbà tí àgbẹ̀ bá dé láti oko tàbí lọ́jọ́ tí kò bá lọ sóko, kí ó lè máa rí nńkan fọwọ́ pa
lásán ni. Nǹkan ọ̀gbìn kì í pọ̀ níbẹ̀ rárá, nǹkan jíjẹ́ ni, kì í sí igi owó bí i kòkó, obì tàbí kọfí níbẹ̀.
Iṣẹ́ àgbẹ̀ ti di èyí tí wọ́n ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé fún lode-òní. Ẹni tí kò bá lówó dáadáa kòlè dáwọ́ lé e.
Irin Iṣẹ́:Àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò ni ọkọ́, àdá, akọ́rọ́, agbọ̀n, ẹní, agbada abbl. Lákòótán, iṣẹ́ àgbẹ̀
jẹ́ èyí tó ń mú owó wọlé fún àwọn tó mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ìlànà bí ó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe
é.
ii. Aró-dídá
Aró-dídá kò nira bí iṣẹ́ àgbẹ̀. Àwọn obìnrin ló máa ń ṣe e. Ẹni tó ń ṣiṣẹ́ yìí gbọdọ̀ wá ibi tó
gbààyè dáadáa tí yóò lè gbé ìkòkò tó tóbi sí. Láyé àtijó, ewé ẹ̀lú ni wọn yóò gún dáadáa, wọ́n á
dà á sínú ìkòkò, wọn yóò sì bu omi sí I láti rẹ ẹ́ fún ọjọ́ díẹ̀ kó bàá lè toró sínú omi. Inú rẹ̀ ni wọ́n
ń rẹ aṣọ tí wọ́ fẹ́ pa láró sí, ibẹ̀ náà ni wọ́n ń rẹ ìkọ́-òwú sí kí ó lè dúdú dáadáa.
5.0. Ìsọníṣókí
Iṣẹ́ àgbẹ̀ àti iṣẹ́ aró-dídá jẹ́ iṣẹ́ tó gbayì láwùjọ Yorùbá. Àwọn iṣẹ́ méjèèjì wọ̀nyí ló jẹ́
kòṣeémánìn-ín láwùjọ. Àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ni wọ́n ti ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé fún kí àyípadà rere lè dé bá
wọn. Àwọn kan sì ń lo irinṣẹ́ ayé àtijọ́ nítorí ọ̀wọ́n owó. Àwọn iṣẹ́ méjèèjì ló ń pèsè fún àwùjọ.
1.0. Ìfáárà
Iṣẹ́ àbáláyé ni epo-fífọ̀ àti gaàrí yíyan láwùjọ Yorùbá, wọ́n sì jẹ́ iṣẹ́ tó gbajúmọ̀ tó lóòrìn
láàrin àwọn iṣẹ́ ìbílẹ̀ yòókù. Iṣẹ́ méjèèjì wọ̀nyí ló jẹ́ pé àwọn obìnrin ló ń ṣe kòkáárí wọn láti
ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Nǹkan gbòógì tí wọ́n ń lò láti ṣe epo ni igi ọ̀pẹ, tí igi ẹ̀gẹ́ sì jẹ́ èyí tí wọ́n ń lò fún
gaàrí. Epo-fífọ̀ àti gaàrí-yíyan máa ń gbà tó ọ̀sẹ̀ kan dáadáa tàbí kó lé díẹ̀. Iṣẹ́ méjèè wọ̀nyí ló
ń mú owó wọlé, bẹ́ẹ̀ náà ló ń pèsè oúnjẹ fún àwọn tó ń ṣe wọ́n àti mọ̀lẹ́bí wọn.
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
i. Epo-fífọ̀
A kò lè sọ̀rọ̀ epo láìfì ti igi ọ̀pẹ ṣe. Oríṣi ọ̀pẹ méjì ló wà, ọ̀pẹ epo àti ọ̀pẹ-ifá. Wọn kì í fi ọ̀pẹ-ifá
ṣepo nítorí pé epo náà yóò máa ru. Ọ̀pẹ ló ń so ẹyìn. Wọn kì í sọ pé ọ̀pẹ so, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n á ní
ọ̀pẹ ladi (la odi). Tí odi ẹyìn bá ti pọ́n lórí ọ̀pẹ, akọ̀pẹ ni yóò gun ọ̀pẹ láti kọ ẹyìn pẹ̀lú igbà rẹ̀.
Igbà lè jẹ́ ọkẹrẹ tàbí ọ̀pàkà. Ọkẹrẹ kì í yá láti gun ọ̀pẹ ṣùgbọ́n ààbò tó ń fún akọ̀pẹ pọ̀ ju ti ọ̀pàkà
lọ. Bí akọ̀pẹ ṣe ń kọ ẹyìn ni wọn yóò má ru odi ẹyìn lọ sí bawò, ibẹ̀ ni akọ̀pẹ yóò ti ṣá ẹyìn kúrò
lára odi rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, wọn yóò bò ó pẹ̀lú imọ̀ ọ̀pẹ fún ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin kí ó bàá lè rọ̀ dáadáa fún
ṣíṣí kúrò lára ṣọṣọ-ẹyìn.
Tí wọ́n bá ṣí ẹyìn tán, wọ́n á rù ú wá sí ẹbu níbi tí wọn yóò ti fọ̀ ọ́ ṣe epo. Wọ́n á kó ẹyìn sínú
ìkòkò ńlá tàbí gorodóòmù. Wọ́n á bu omi sí i, wọ́n á gbé e sórí iná láti sè é fún bi wákàtí mẹ́ta sí
mẹ́rin. Tí ẹyìn bá jinná, wọ́n yóò dà á sínú odó láti gún un tàbí kí wọ́n máa fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ fún ọgbọ̀n
ìṣẹ́jú. Lẹ́yìn gígún tàbí títẹ ẹyìn, wọ́n yóò dà á sínú ẹkù tí wọn pọn omi sí. Bí wón ṣe ń fọ̀ ọ́ ni
wọn yóò máa kóèyí tó ki lọ̀kọ̀tì, tí wọn yóò máa dà á sínú ìkòkò tàbí àgbá tó wà lórí iná láti sè é
fún ìgbà pípẹ́. Kí wọ́n tó kúrò nínú ẹkù, wọ́n á yọ èkùrọ̀ àti ihá sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n á sì gbọ́n omi inú
ẹkù sí ibi tí kò ti ní rí ààyè ṣàn lọ. Tó bá tó bí ọjọ́ mẹ́ta, omi yìí yóò ti di, wọ́n yóò kó o lọ sílé láti
lẹ̀ ẹ́ mọ́ ògiri tàbí kí wọn lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara àwọn ọ̀pá tí wọ́n ti pèsè sílẹ̀ Èyí ni wọ́n ń pè ní ṣùgùdù tàbí
ògùnṣọ̀. Tó bá gbẹ, wọn yóò máa fi tanná tàbí dáná.
Èyí tó ki tí wọ́n dà sórí iná ni wọn yóò sè dáadáa tí epo yóò fi léfòó sórí omi. Wọ́n á ré/yọ epo
kúrò lórí omi, wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ tún epo náá sè dáadáa. Ó ti di epo nìyẹn. Wọ́n á padà sídìí àgbá tí wọ́n
ti ré epo láti yọ ìkẹ̀tẹ́. Dúdú ni àwọ̀ ìkẹ̀tẹ́, wọ́n máa ń fi òun náà jẹ iṣu.
Ọ̀pẹ
Igbà (ọkẹrẹ àti ọ̀pàkà)
Odó
Ẹkù
Ìkòkò/àgbà/gorodóòmù
Bawò
Odi-ẹyìn
Omi
Iná
Ẹbu
Àáké
Tí gbogbo àwọn nǹkan tí a tò sókè yìí bá ti pésẹ̀, iṣẹ́ epo-fífọ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu.
ii. Gaàrí-yíyan
Gaàrí-yíyan wọ́pọ̀ níl;ẹ̀ Yorùbá. Wọ́n á wú ẹ̀gẹ́, wọ́n á rin ín lórí gérétà. Láyé òde-òní, ẹ̀rọ
ìgbàlódé ni wọ́n fi ń rin ẹ̀gẹ́. Wọ́n á kó o sínú apẹ̀rẹ̀ di ọjọ́ kejì kí ó lè ro omi. Wọ́n á kó o sínú
ṣaka, wọ́n á dì í lẹ́nu dáadáa, wọ́n á wá di ẹrù tó wúwo lé e lórí fún ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin kí ó bàá lè
wami dànù, àti pé kí ó lè kan dáadáa tí wọn bá yan án tán. Wọ́n á kó o sórí ajọ̀ láti jọ̀ ọ́. Lẹ́yìn
èyí, wọ́n á kó o sínú agbada tí wọ́n dáná sábẹ́ rẹ̀. Wọ́n á bẹ̀rẹ̀ síí yan án títí tí yóò fi gbẹ. Wọ́n á
kó o kúrò nínú agbada. Gaàrí ti dé nìyẹn.
5.0. Ìṣọníṣókí
Bí wọ́n ṣe ń fọ epo àti bí wọ́n ṣe ń yan gaàrí la sọrọ lórí rẹ̀. A mẹ́nuba àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò fún
wọn. Ìyàtọ̀ díẹ̀ ti dé bá àwọn iṣẹ́ ìbílẹ̀ méjèèjì wọ̀nyí. Tọkùnrin tobìnrin ló ń kópa nínú àwọn iṣẹ́
méjèèjì.
6.0. Iṣẹ́ Ṣíṣe
1. Ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ bí wọ́n ṣe ń fọ epo.
2. Ṣe àpèjúwe ìyàtọ̀ tó dé bá bí wọ́n ti ń yan gaàrí láyé àtijọ́ àti lode-òní.
1.0. Ìfáàrà
Àṣà tó rinlẹ̀ ni ìranraẹnilọ́wọ́ ní àwùjọ Yorùbá. Àáró, àjọ àti èésú jẹ́ ọ̀nà tí àwọn Yorùbá ń gbà
ran ara wọn lọ́wọ́ láyé àtijọ́, a sì ń rí i díẹ̀díẹ láyé òde-òní. Ó jẹ́ àṣà tó ń mú ìlọsíwájú bá àwùjọ
àṣùwàdà ènìyàn láìsí ìnira. Òótọ́ àti ìfọkàntán ni àwọn to ń ṣe é ń fi bá ara wọn lò.
4.0. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
Àáró
Àáró jẹ́ àṣà tí àwọn Yorùbá fi ń ran ara wọn lọ́wọ́ láyé àtijọ́. Gbogbo oníṣẹ́ ìbílẹ̀ ló máa ń lo
àáró.ì bá à jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Àwọn tó ń ṣe àáró gbọdọ̀ ní agbára láti ṣiṣẹ́ bákan náà. Àwọn
tó ń ṣàááró lè tó mẹ́ta, mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ,ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni wọn yóò máa fi lọ sóko ọmọ ẹgbẹ́ wọn.
Ẹni tí àáró bá kàn yóò wá oúnjẹ fún àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù. Báyìí ni wọn yóò máa ṣe títí tí yóò fi
kárí.
Àjọ
Àṣà yìí jẹ́ èyí tó nípọn díẹ̀ nítorí ó la owó lọ, fún ìdí èyí, ènìyàn gbọdọ̀ ní ẹ̀mí ìfọkàntán dáadáa kí
ó tó lè gbé owó rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹnìkan láti máa tọ́jú. Ó lè jẹ́ ìparí ọdún ni wọn yóò tó kó àjọ lọ́wọ́ ẹni
tí wọ́n ń dá a sí. Ọjọ́ kan náà náà ni àjọ yóò parí, tí gbogbo wọn yóò sì kó nǹkan tí wọ́n bá dá.
Èésú
Èésú náà ní ọ̀rọ̀ owó nínú. Ẹnìkan ni yóò máa gba owó sọ́wọ́. Tí wọ́n bá ti dá a, wọn yóò kó o
fún ẹnìkan títí yóò fi kárí. Ìdí rèé tí wọ́n fi ń pa á lówe pé ẹni èsúsú ba torí ẹ̀ tú, kò ní bá wọn
dábàá àkógbẹ̀yìn.
Lákòótán, àwọn ọ̀nà tí àwọn Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́ tó fi ń dẹ̀ wọ́n lọ́rùn láti gbé nǹkan
ribiribi ṣe láyé àtijọ́ nìyí.
5.0.Ìsọníṣókí
Ọ̀nà tí àwọn Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́ láyé àtijọ́ ni àáró, àjọ àti èésú. Ilé ìfowópamọ́
ìgbàlódé sì ti ń gba ipò àjọ àti èésú báyìí, àfi ọ̀dọ̀ àwọn aláròóbọ̀ nínú ọjà ló wọ́pọ̀ sí báyìí.
6.0. Iṣẹ́ Ṣíṣe
1. Kọ àròkọ kíkún lórí àáró.
2. Ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí èésú àti àjọ, kí o sì sọ ìyàtọ̀ tó ń dé bá wọn lóde-òní.
1.0. Ifáárà
Àgbéyẹ̀wò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kínní títí déì kẹrin ni a óò sọ̀rọ̀ lé lórí, àṣà ajẹmọ́ṣẹ̀ṣe, àṣà àrídìmú láwùjọ
Yorùbá, ìṣẹ̀ṣe ajẹmáyẹyẹ, ajẹmọ́bọ lórí ọdún ìbílẹ̀, ìṣẹ̀ṣe ajẹmórin ìbílẹ̀ àti ìṣẹ̀ṣe ajẹm-éré-mọdé.
Gbogbo ẹ̀yà lágbàáyé ló ni àṣà tí wọ́n ń tẹ̀lé tó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí atọ́nà fún wọn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yà Yorùbá
ní tirẹ ń jẹ́ kí tèwe tàgbà wọn mọ nǹkan tó tọ́ àti tó yẹ láti ṣe. Àkóónú àṣà Yorùbá pọ̀ débi pé a lè
sọ pé kò lóǹkà. Àṣà wà látorí ìbágbépọ̀ láwùjọ títí tó fi dórí ìgbéyàwó, ìsọmọlórúkọ, ẹgbẹ́, ọ̀gbà,
iṣẹ́ ìbílẹ̀, ìranraẹnilọ́wọ́, oúnjẹ, aṣọ-wíwọ̀, ìtọ́jú ara-ẹni tàbí oge-ṣíṣe, ẹ̀kọ́-ilé, abbl. Yàtọ̀ sí pé a
sọ̀rọ̀ lórí mélòó kan nínú kọ́ọ̀sì yìí, ìyànjú yóò wáyé láti pín gbogbo wọn sí ìsọ̀rí méjì tí a lè pè ní
àṣà ajẹmọ́ṣẹ̀ṣe àti àṣà àrídìmú. Nínú ìdánilẹ́kọ̀ó yìí, a ti ṣàlàyé nǹkan tí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan jẹ́, kí wọn
bàá lè yé mùtúmùwà dáadáa.
Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, a ṣàlàyé lórí àṣà ajẹmáyẹyẹ àti ajẹmọ́bọ ní àwùjọ Yorùbá. Ìṣẹ̀ṣe ajẹmáyẹyẹ
ni àṣà tí kò ní ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tàbí ètùtù nínú. Ìṣẹ̀ṣe ajẹmọ́bọ ni a lè pè ní àṣà tó jẹmọ́ ẹ̀sìn, ètùtù, òrò, àti
awo ṣíṣe. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí jẹ́ kó yé ọ pé kì í ṣe gbogbo àṣà Yorùbá ló níí ṣe pẹ̀lú Òrìṣà bíbọ.
Orin ìbílẹ̀ pọ̀ láwùjọ débi pé bí a ṣe rí èyí tó jẹ mọ́ ayẹyẹ náà ni èyí tó wà fún àwọn Ìbọ pọ̀. Oríṣìí
ewì kan ni orin náà jẹ́ ní àwùjọ Yorùbá. Ọ̀kan-ò-jọ̀kan orin ló sì wà ní ìkáwọ́ àwọn Yorùbá.
Àmúlùúdùn ni orin jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ló si jẹ́ adàlúrú, ṣé orin ló kúkú ń ṣáájú ọ̀tẹ̀. Oríṣìí méjì ni a lè pín
orin Yorùbá tó jẹ́ ti àbáláye sí:
i. orin ajẹmẹ́sìn
ii. orin ayẹyẹ
Orin ajẹmẹ́sìn ni orin tí wọ́n ń kọ nídìí Òriṣà, yálá nígbà ọ̀sẹ̀ tàbí ọdún Òriṣà. Irúfẹ́ orin yìí wọ́pọ̀
láàrin àwọn Yorùbá. Orin Ọ̀sanyin ni wọ́n fi ń ṣọdún Òriṣà Ọ̀sanyin ni ilú Osùn-ún Èkìtì
(Orímóògùnjẹ́, 1986). Orin Ògún ni wọ́n ń kọ nígbà ọdún Ògún ní agbègbè Ìjerò Èkìtì
(Aládésòfi, 1986). Orin àgbọn ni wọ́n ń kọ ní Ilé-Ifẹ̀ ní àkókò ọdún Àgbọn. Àwọn Olórìṣà
Ọbàtálá náà ní orin tiwọn nídìí Òòṣà wọn.
Erémọdé tàbí eréṣùpá kún fún oríṣiríṣi ewì, ọ̀rọ̀-geere àti ewì tí àwọn Yorùbá fi ń dáni lára yá,
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ náà. A ti ṣàlàyé lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ lórí àlọ́-onítàn (àlọ́-àpagbè), àlọ́-àpamọ̀,
orin àlọ́ (orin-eréṣùpá) àti àrọ̀.
1.0. Ìfáárà
Ìdanilékọ̀ọ́ karù-ún sí ìkẹjọ dá lórí ẹ̀kọ́-ilé, ìsìnkú, ìgbéyàwó àti ìsọmọlórúkọ. Ìgbàgbọ́ àwọn
Yorùbá ni pé ọmọ tí wọn kò kọ́ ni yóò gbé ilé tí wọ́n kọ́ tà. Ìdí rèé tí wọ́n fi ń sọ pé ó pọn dandan
kí òbí má máa lé owó nìkan bí kò ṣe pé kí wọ́n ṣe ojúṣe wọn lórí ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn. Láti
kékeré ni Ìmọ̀le ti ń kọ́mọ rẹ ḷẹ́sìn. Áti inú oyún ni Yorùbá sọ pé ó yẹ kí òbí ti máa kọ́ ọmọ wọn.
A ti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àlàyé lórí àwọn ìgbésẹ̀ bí ẹ̀kọ́ àbínimọ́. ẹ̣̀kọ́ ìṣirò àti ẹ̣̀kọ́ erémọdé tó wà nínú ẹ̀kọ́-
ilé.
A jẹ́ kó di mímọ̀ pé ‘àwáyéèkú kan kò sí, ọ̀run nìkan làrèmọ́bọ̀; kò sẹ́ni tí kò níí kú, tóko baba rẹ̀
kò níí dìgbòrò’. Yorùbá kì í banújẹ́ lórí ikú, àfi tó bá jẹ́ pé ọmọdé tàbí ọ̀dọ́ ló kú. Òkú ẹ̀kọ àti
àmàlà, ìdùnnú àti ayẹyẹ ni wọ́n ka òkú àgbà sí. Oríṣiríṣi ikú tó ń pa ẹ̀dá tí a mẹ́nubà ni, òkú àgbà,
òkú ọmọdé, òkú ọ̀dọ́, òkú abínúkú, òkú ẹni tí Òrìṣà/Ìbọ pa, òkú aboyún, òkú adẹ́tẹ̀, òkú abuké,
òkú Ọba àti òkú Ọdẹ.
Ni ti ìgbéyàwó, a jẹ́ ká mọ̀ pé, nílẹ̀ Yorùbá, ọkùnrin ló máa ń ṣètò láti ní ẹbí. Nǹkan tí a ní lọ́kàn
ni pé ọkùnrin ló ń wá ìyàwó, kì í ṣe obìnrin ló ń wá ọkọ. Èto ìgbéyàwó ní ìgbésẹ̀ tó mọ́yán lórí, ó
sì wà ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé; ìfojúsóde, alárinà, ìdẹ̀giri, ìjọ́hẹ̀n, ìtọrọ-ọmọ, ìdána àti ayẹyẹ ìgbéyàwó.
Ọmọkùnrin tí kò tíì ní ìyàwó ni wọ́n ń pè ní àpọ́n. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àwàdà, oríṣi àpọ́n mẹ́ta ló wà.
Èkínní ni àpọ́n mo ń wòye (ọmọkùnrin tó ń wóbìnrin tó wù ú), èkejì ni àpọ́n mo róye (ọmọkùnrin
tó rẹ́ni tó wù ú) àti àpọ́ ṣa-n-ko (ọmọkùnrin tí kò ní ìyàwó, tí kò sì ní in lọ́kàn láti ní). Ọmọkùnrin
yóò máa wá obìnrin tó lè fẹ́ títí tí yóò fi rẹ́nìkan. Tó bá ti rẹ́ni tí ó wù ú, yóò wá ẹnìkan tí yóò jẹ́
alárinà. Alárinà ni ọmọkùnrin yóò máa rán sí ọmọbìnrin, tí yóò sì máa fún ọkùnrin lésì títí tí
àwọn méjèèjì yóò fi fojú kanra. Iṣẹ́ alárinà ti kásẹ̀ nílẹ̀ nìyẹn bí wọ́n bá ti fojú kan ara wọn. Ìdí
rèé tí wọ́n fi ń sọ pé bí aya bá ti mojú ọkọ tán, alárinà a yẹ̀ba.
A rí i pé orúkọ ṣe pàtàkì, ìdí rèé tí ẹnikọ̀ọ̀kan ṣe ń ní orúkọ tirẹ. Ìsọ̀rí bíi mẹ́ta ni a lè pín orúkọ sí:
àwọn náà ni orúkọ àbísọ, orúkọ àmútọ̀runwá àti oríkì. Láyé àtijọ́, ọjọ́ keje ni wọ́n ń sọ ọmọbìnrin
lórúkọ, ọjọ́ kẹsàn-án ni ti ọmọkùnrin, tí ọjọ́ kẹjọ sì jẹ́ ti àwọn ìbejì. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ láyé òde-òní,
ọjọ́ kẹjọ ni gbogbo ọmọ. Ní ọjọ́ ìsọmọlórúkọ, ọ̀pọ̀ èròjà tẹ́nu ń jẹ ní wọn yóò kó sílẹ̀ láti wúre fún
ọmọ tuntun. Lára àwọn èròjà náà ni: ìrèké, ataare, àádùn, omi, iyọ̀, ọ̣̀bẹ, oyin, orógbó àti epo. A
sì sọ ọ́ di mímọ̀ pé ọ̣̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn èròjà wọ̀nyí ló ní àrokò tí wọ́n ń pa fún ìgbé-ayé ọmọ
tuntun náà.
1.0. Ìfáárà
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kẹsàn-án dé ìkejìlá dá lórí oyè-jíjẹ; iṣẹ́ àgbẹ̀ òun aró-dídá; epo-fífọ̀ pẹ̀lú gaàrí-yíyan;
àti àáróàjọ títí kan èésú-dídá. Lára nǹkan tí a sọ ni oyè-jíjẹ láwùjọ Yorùbá láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Nínú
ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, oyè-jíjẹ bẹ̀rẹ̀ láti orí olórí ẹbí tàbí tí a tún lè pè ní Mọ́gàjí níbòmìíràn, tó fi dórí
Baálẹ̀, Ìjòyè àti Ọba ìlú. Láyé àtijọ́, kí wọn tó fi ẹnikẹ́ni joyè tàbí sí ipò aláṣẹ, wọn yóò dá gbé Ifá
sí i kí wọnbaà lè mú ẹni tí yóò ṣe ìlú láǹfààní . Èyí tó pọn dandan lóde-òní ni ti Ọba, láti béèrè
lọ́wọ́ Ifá kí wọn tó yan Ọba.
Iṣẹ́ àgbẹ̀ àti aró-dídá la tún ṣàlàyé dáadáa nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó kọjá. Ọkùnrin ni a mọ̀ mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀
tó sì jẹ́ pé obìnrin ló jẹ́ gbajúgbajà nidìí aró-dídá. Oríṣiríṣi ọ̀nà ní iṣẹ́ àgbẹ̀ pín sí, Nǹkan tó jẹ mọ́
ọ̀gbìn ni a lè pè ní iṣẹ́ àgbẹ̀ láwùjọ Yorùbá láyé àtijọ́. Oríṣiríṣi irinṣẹ́ ló rọ̀ mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló
rí fún aró-dídá. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ti tú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn palẹ̀ kí o fi le mọ bí ìran Yorùbá ṣe
kááràmásìkí wọn sí.
Ó hàn gbangba nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí pé iṣẹ́ àbáláyé ni epo-fífọ̀ àti gaàrí-yíyan láwùjọ Yorùbá, wọ́n
sì jẹ́ iṣẹ́ tó gbajúmọ̀, tó lóòrìn láàrin àwọn iṣẹ́ ìbílẹ̀ yòókù. Iṣẹ́ méjèèjì wọ̀nyí ló jẹ́ pé àwọn
obìnrin ló ń ṣe kòkáárí wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Nǹkan gbòógì tí wọ́n ń lò láti ṣe epo ni igi ọ̀pẹ, tí igi
ẹ̀gẹ́ sì jẹ́ èyí tí wọ́n ń lò fún gaàrí. Epo-fífọ̀ àti gaàrí-yíyan máa ń gbà tó ọ̀sẹ̀ kan dáadáa tàbí kó lé
díẹ̀. Iṣẹ́ méjèèjì wọ̀nyí ló ń mú owó wọlé, bẹ́ẹ̀ náà ló ń pèsè oúnjẹ fún àwọn tó ń ṣe wọ́n àti
mọ̀lẹ́bí wọn.
Àṣà ìranraẹnilọ́wọ́ dá lórí àáró, àjọ àti èésú láwùjọ Yorùbá, ó jẹ́ ọ̀nà tí àwọn Yorùbá ń gbà ran ara
wọn lọ́wọ́ láyé àtijọ́, a sì ń rí i díẹ̀díẹ láyé òde-òní. Ó jẹ́ àṣà tó ń mú ìlọsíwájú bá àwùjọ àṣùwàdà
ènìyàn láìsí ìnira. A rí i dájú pé òótọ́ àti ìfọkàntán ni àwọn to ń ṣe é ń fi ń bá ara wọn lò.
Ìgúnlẹ̀
Ní báyìí, tí a ti wakọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yì́́í́ gúnlẹ̀, tí o sì ti kà á dáadáa ní àkàyé àti àkàgbádùn gẹ́gẹ́ bí
èrò mi, àdúrà mi fún ọ ni pé; Àṣeyè lo ó ṣe o, nítorí pé àṣeyè ni alákàn ń ṣepo.
IRE O!