Onka Yoruba: Numbers 1 to 1000
Onka Yoruba: Numbers 1 to 1000
ALIFABĘĘTI YORUBA
Leta Marun-undinlogbon (25 letters) lowa ninu alifabęęti Ede Yoruba. O tumosi wipe a ni
faweeli meje (7 vowels) pelu Konsonanti mejidinlogun (18 consonants).
Awon Niwoyi: A,B,D,E,Ę,F,G,GB,H, I,J,K,L,M,N,O,O,P,R,S,S,T,U,W,Y
ONKA YORUBA
Numbers In Yoruba - Onka Yoruba
1 – Ookan
2 – Eeji
3 – Eeta
4 – Eerin
5 – Aarun
6 – Eefa
7 – Eeje
8 – Eejo
9 – Eesan
10 – Eewa
11 – Ookanla
12 – Eejila
13 – Eetala
14 – Eerinla
!5 – Eedogun
16 – Eerindinlogun
17 – Eetadinlogun
18 – Eejidinlogun
19 – Ookandinlogun
20 – Ogun/Okoo
21 – Ookanlelogun
22 – Eejilelogun
23 – Eetalelogun
24 – Eerinlelogun
25 – Eedogbon
26 – Eerindinlogbon
27 – Eetadinlogbon
28 – Eejidinlogbon
29 – Ookandinlogbon
30 – Ogbon
31 – Ookanlelogbon
32 – Eejilelogbon
33 – Eetalelogbon
34 – Eerinlelogbon
35 – Aarundinlogoji
36 – Eerindinlogoji
37 – Eetadinlogoji
38 – Eejidinlogoji
39 – Ookandinlogoji
40 – Ogoji
41 – Ookanlelogoji
42 – Eejilelogoji
43 – Eetalelogoji
44 – Eerinlelogoji
45 – Aarundinlaadota
46 – Eerindinlaadota
47 – Eetadinlaadota
48 – Eejidinlaadota
49 – Ookandinlaadota
50 – Aadota
51 – Ookanlelaadota
52 – Eejilelaadota
53 – Eetalelaadota
54 – Eerinlelaadota
55 – Aarundinlogota
56 – Eerindinlogota
57 – Eetadinlogota
58 – Eejidinlogota
59 – Ookandinlogota
60 – Ogota/Ota
61 – Ookanlelogota
62 – Eejilelogota
63 – Eetalelogota
64 – Eerinlelogota
65 – Aarundinlaadorin
66 – Eerindinlaadorin
67 – Eetadinlaadorin
68 – Eejidinlaadorin
69 – Ookandilaadorin
70 – Aadorin
71 – Ookanlelaadorin
72 – Eejilelaadorin
73 – Eetalelaadorin
74 – Eerinlelaadorin
75 – Aarundinlogorin
76 – Eerindinlogorin
77 – Eetadinlogorin
78 – Eejidinlogorin
79 – Ookandinlogorin
80 – Ogorin/Orinn
81 – Ookanlelogorin
82 – Eejilelogorin
83 – Eetalelogorin
84 – Eerinlelogorin
85 – Aarundinlaadorun
86 – Eerindinlaadorun
87 – Eetadinlaadorun
88 – Eejidinlaadorun
89 – Ookandinlaadorun
90 – Aadorun
91 – Ookanlelaadorun
92 – Eejilelaadorun
93 – Eetalelaadorun
94 – Eerinlelaadorun
95 – Aarundinlogorun
96 – Eerindinlogorun
97 – Eetadinlogorun
98 – Eejidinlogorun
99 – Ookandilogorun
100 – Ogorun
200 - Igba
300 - Oodunrun
400 - Irinho / Irinwo
500 - Eedegbeta
600 – Egbeta
700 – Eedegberin
800 – Egberin
900 – Eedegberun/Orundinlegberun
1,000 – Egberun
The seven days are: Ọjọ́-Àìkú (Sunday), Ọjọ́-Ajé (Monday), O̩ jọ́-Ìṣẹ́gun (Tuesday),
Ọjọ́rú (Wednesday), Ọjọ́bo̩ (Thursday), Ọjọ́-E̩ tì (Friday) and O̩ jọ́-Àbamé̩ ta
(Saturday).
Time (Ìgbà, àsìkò, àkókò) is measured in ìṣẹ́jú-àáyá (seconds), ìṣẹ́jú (minutes), wákàtì
(hours), ọjọ́ (days), ọ̀sẹ̀ (weeks), oṣù (months) and ọdún (years).
There are 60 seconds (ọgọ́ta ìṣẹ́jú-àáyá) in 1 minute (ìṣẹ́jú kan); 60 minutes (ọgọ́ta
ìṣẹ́jú) in 1 hour (wákàtì kan); 24 hours (wákàtì mẹ́rìnlélógún) in 1 day (ọjọ́ kan); 7 days
(ọjọ́ méje) in 1 week (ọ̀sẹ̀ kan); 4 or 5 weeks (ọ̀sẹ̀ mẹ́rìn tàbí márùn-ún) in one month
(oṣù kan); 52 weeks (ọ̀sẹ̀ méjìléláàádọ́ta), 12 months (oṣù méjìlá), and 365 days (ọjọ́
mẹ́rìndínláàádọ́rinlélọ́ọ̀ọ́dúnrún) in 1 year (ọdún kan).
Ṣẹrẹ/January
Dedicated to Obatala
Èrèlé/February
Èrèlé/Feb 21-25
Ẹrẹ́nà/March
Ẹrẹ́nà/March 12 – 28
Ẹrẹ́nà/March 15 – 19
Igbe/April
Èbìbí/May
Òkúdù/June
Agẹmo/July
Ògún/August
Ọwẹ́wẹ̀ or Owewe/September
Ọ̀wàrà or Ọ̀wààrà/October
Belu/November
Ọ̀pẹ/December
Fáwẹ̀lì Yorùbá
Fáwẹ̀lì ni ìró tí a pè tí kò sí ìdiwọ́ fún afẹ́fẹ́ tàbí èémí tÍ ó ń ti inú ẹ̀dọ̀ fóró bọ̀ wá
sí ọ̀nà ẹnu. Bí àpẹẹrẹ: a, e, ẹ, i, o, ọ, u, an, ẹn, in, ọn, un,.
Gbogbo ìró fáwẹ̀lì èdè Yorùbá ló jẹ ìró akùnyùn. Èyí ni pé tán-án-ná gbọ̀n rìrì
nígbà tí a pè wọ́n.
Oríṣi méjì ni fáwẹ̀lì èdè Yorùbá, àwọn ìsọ̀rí méjì náà ni…Fáwẹ̀lì àìránmúpè àti
fáwẹ̀lì àránmúpè
SILEBU EDE YORUBA
Silebu ni ege oro ti o kere ju ti eemi le gbe jade leekan soso. A tun le pe silebu ni ege ti o
kere ju ti a le e pin eyo oro kan si nipa lilo eemi. (b.a a,e,e,I,o,o,u, an,en,in,on,un)
wa,ko,[Link], mu, na,abbl.
AROKO (EMISSARY)
Awon Yoruba ni awon ona ti won n gba ba ara won soro asiri ni aye
won yoo fi ranse, ti ami naa yoo si tumo ara re. Fifi nkan ranse bi ami
lati fi oye pataki kan ye eni ti a fi nkan naa ranse sii ni a n peni aroko.
Aroko ni ami tabi ona ede ti o leje oro kan tabi omiran ti a le lo lati fi
ba ara eni soro lona ijinle, eyi ti yoo fun wa ni orisirisi itumo ti o yato
si ohun ti ami naa je. Kii se gbogbo aroko ni a fi n ranse si ni. Awon
ni a n fi won si eyi yoo fun Iru eni bee ni anfaani lati le tete ri.
ORISII AROKO
i. Aroko ikilo
1. AROKO IKILO: Bi eniyan ba n huwa aito bii fife iyawo ile elo miiran,
ole jija tabi huwa odaran tabi ika. Won le paroko ranse si iru eni bee ki
onitohun je e. Apeere:
14. Iyepe didi lewe ranse: Ebe tabi imule ki eniyan ma dale.
15. Kanhin kanhin tuntun ati ose: Iyawo eni naa ti bimo tuntun.
17. Eyin aja ati osun: Fi oro naa se osun kofi raara (aja kii sa n omo re
de eegun)
1. Eesan: Eyi tumo sipe iroyin aburu ni won gbo si eni naa
3. Ti ilu kan ba fi ata ati iyo ranse si ilu keji: Won ti ni ikunsinu ara won
baa ko sinu ewu tabi isoro. A kii fi aroko yii ranse, ogangan ibi ti yio ti
1. Ti won ba fi eeru si ori ewe ni eba ona Ode kan wa nitosi ibe tabi pe
2. Ti won ba ta mariwo tabi aso si oju ona Enikeni ko gbodo gba oju
Àkíyèsí sí wà pé kò sí èdè tàbí àwùjọ kan tí kì í ya ọ̀rọ̀ láti inú èdè kan, bí Gẹ̀ẹ́ṣì
ṣe yá ọ̀rọ̀ bẹẹ náà ni àwùjọ Yorùbá náà yá ọ̀rọ̀, bí ó sì ṣe wà káàkiri nínú
gbogbo èdè àgbáyé.
Oro – ayalo -: ni awon oro ajeji ti a maa n ya wonu ede Yoruba lati inu
ede miiran
Oro – ayalo -: ni mimu oro lati inu ede kan wo inu ede miiran lona ti pipe
ati kiko re yoo fi wa ni ibamu pelu ede ti a mu-un wo.
Bakan naa, o maa n je ki oruko wa fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba
n sese n wo awujo wa
1) Àfetíyá
2) Àfojúyá
Ilana afetiya -: eyi ni pipe oro ayalo ni ona to sunmo bi awon elede se n
pe oro gan-a
Bible – Baibu
Peter – Pita
Table – Tebu
Esther – Esita
Deacon – Dikin
Council – kansu
Soldier – soja
Table – tabili
Peter – peteru
Esther – esiteri
Bible – Bibeli
Deacon – Diakoni
Paradise – paradise
Hebrew – Heberu
Ede Geesi
Ede Larubawa
Ede Faranse
Ki oro ede Geesi ti a ya lo to le di ara oro ninu ede Yoruba, o gbodo tele
ofin ede Yoruba
Bread – buredi
Quran - Kurani
Gum – goomu
Bed – beedi
Shirt – seeti
fail – feeli
Glass – gilaasi
Gold – goolu
Angel - angeli
Mobil – mobi
Moses – mose
Jesus – jesu
Lazarus – lasaru
iii. Yiya isupo konsonanti oro- ayalo, fifi faweli ya isupo konsonanti:
bread – buredi
milk – miliiki
Tray – Tiree
Station – Tesan
Belt – beliiti
Lazarus – lasaru
Church – soosi
Queen – kun-yin
Valve – faafu
Stamp – sitanbu
Cup – koobu
OWE YORUBA
Òwe ni ohùn ìjìnlẹ̀ ẹnu àwọn àgbà-gbà ní ilẹ̀ Yorùbá tí ó kun fún ọgbọ́n,
ìmọ̀, ìṣítí, ìkìlọ̀, àti òye àwọn bàbá ńlá baba wa ní ilé káàrọ̀-o-ò- jíire.
Àwọn àgbà-gbà Yorùbá ma ń ṣe àmúlò òwe láti lè sọ́ra fún àsọjù tàbí
Ìsọ̀rí òwe
Òwe Ìkìlọ̀
Òwe yí ni wọ́ n ma ń ló láti kìlọ̀ ìwà pàá pàá jùlọ ìwà ẹ̀gbin àti
Òwe Ẹ̀kọ́-ilé
Yorùbá ma ń fi òwe yí kọ́ àwọn ọmọ wọ́n bí wọ́n tile ṣojú àwọn òbí wọn ati bí
wọ́n ṣe lè hùwà láwùjọ. Àpẹẹrẹ irúfẹ́ òwee bẹ́ẹ̀ ni:
Wọ́ n ma ń fi òwe yí lani lọ́ yẹ̀ tàbí gbani níyànjú lórí àwọn ọrọ̀
Translation: When a king's palace burns down, the re-built palace is more beautiful.
Translation: All lizards lie flat on their stomach and it is difficult to determine
which has a stomach ache
Meaning: Everyone looks the same on the outside but everyone has problems
that are invisible to outsiders.
Meaning: A man cannot give what he does not have good or bad behavior is a
reflection of one’s background.
1. A pę ko to jęun, ki ję ibaję
Translation: The person that eat late, will not eat spoiled food
Meaning: If an important man does not respect those less important than
himself, less important men will in turn refuse to give him his due.
Translation: No one rides a horse without moving his head, voluntarily or involuntarily.
Meaning: Your status in life dictates your attitude towards your peers
Translation: He who throws a stone in the market will hit his relative
Meaning: Be careful what you do unto others it may return towards you or
someone close to you
Translation: Little by little is how the pig’s nose enters the yard
1. A ti kekere lati n p’eitan iroko nitori pe to ba dagba tan a ma gba ebo lowo
eni
Meaning: Training of a child commences when the child is still very young and
impressionable; otherwise his training become s late and an uphill task.
Translation: A man’s head with an evil mind does not curve like cutlass for
one to know it.
Translation: He who does not have an antidote for a disease called “adoado”
should not swallow a cockroach.
Meaning: One should avoid any thing or act that will have adverse effect on
him/her.
Meaning: avoid doing things that will have serious repercussion or effect
Translation: If a drum is sounding “kill him, kill him” one should dance to it
with caution.
Meaning: Avoid doing things that will have serious repercussion or effect
Translation: The eye that will be useful to its owner does not start discharging
in the morning.
Meaning: Every human being has special characteristics that make him
unique.
Translation: the water that one is destined to drink will never flow past one.
Meaning: One should not over do things. There should be some restraint.
1. Nkan ti agbalagba bari lori ijoko, omode kole ri lori iduro
Translation: What an elder sees while sitting down, a child can never see it
while standing up.
Translation: The pointed stick that will pierce one in the eye, is avoided while it
is still far off.
Meaning: It is good to show appreciation for any good deed done to one.
1. Opin ohun gbogbo o san ju ibere re lo. (Koto yo si, tiko batii dale)
.
Translation: A good beginning is of no value unless one perseveres to the end.
Translation: A dog does not eat the bone, which is hung on its neck.
Translation: He who does not have himself but claims he has somebody’s
support, suffer will kill him.
Meaning: He who does not help himself but relies on others will suffer.
Meaning: Train your child so that he can give you peace of mind.
Translation: One’s relation cannot be on the top of a cherry tree and one eats
an unripe one.
Meaning: Someone in an influential position should use his position for the
benefit of his relation and community.
What you plant, is what you will pluck, you cannot plant okro and you pluck
cocoa.
1. Oro lo n yo obi l’apo (pocket). Oro naa lo n yo ida ninu apo (sheath)
Translation: A gentle voice brings kola from the pocket while a harsh voice
brings out a sword from its sheath.
Translation: No matter how heavy the body may be the owner will still be able
to carry it.
Translation: The fact that the horse throws down the rider does not stop the
rider from getting up and climbing it again.
Translation: If one acknowledges one’s guilt in court one will not remain on
his knees for long.
Meaning: If you own up to your guilt, you have tried to put things right and so
may be pardoned or judged with leniency.
Translation: The thief who steals the king’s trumpet will find it difficult to blow
it anywhere without being discovered.
AKANLO EDE
Àkànlò-èdè ni ìpèdè tàbí ìṣòro ni ṣókí ṣókí tí ó kún fún ìjìnlẹ̀ ọ̀ rọ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ sì
farasin. A ma n fi àkànlò-èdè ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀ pọ̀ ọ̀ rọ̀ sínú gbólóhun kan ni ṣókí
nínú èdè Yorùbá.
Àkànlò-èdè jẹ́ lílo ọ̀ rọ̀ tàbí awẹ́-gbólóhùn lọ́nà tó jinlẹ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ sí
ìtumọ̀ òrèfé. Oun ni ìpèdè tí gbólóhùn inú rẹ̀ kò ní ǹǹkankan ṣe pẹ̀ lú ìtumọ̀ rẹ̀ .
Júbà ehoro
Gbèkurujẹ l'ọ́wọ́ ẹbọra
Ṣe àyà gbàngbà
Fárígá
Fi àáké kọ́rí
F'apá jánú
Jẹ orí ahun, atbbl.
Akanlo ede Akanlo ede je ipede to kun funijinle oro eyi ti itumo won farasin pupo. O wulo
ni opolopo igba ti a ba fe pe oro so. Apeere akanlo ede ni Fewo jale Buyaari joju pupo Fi
ese fe Salo Abuda akanlo ede Awon abuda akanlo ede ni
(B) Apeere akanlo ede apola: Ru igi oyin- Daran. Teri gbaso, Tateru nipa, pagoda-Ku.
(C) Eyi ni lilo akanlo-ede ti a ti gbe yewo ni gbolohun lati fi itumo won han.
Iya ibeji tuto soke osi fi oju gba a nigba ti o gbo pe omo re feraku.
AAYAN OGBUFO
Ayan ogbufo ni titumo edekan si omiran. Apeere ni titumo ede Geesi si ede
Yoruba;
5. Lilo akoto ati ojulowo ede Yoruba lati fi se ogbufo se Pataki, abbl.
Apeere:
Amongst everything God created you are the most beautiful because you
are created in His image and likeness .God created you to be like Him and
function like Him. You are His excellent handiwork , He created you for
glory and beauty.
ITUMO NI EDE YORUBA Ninu gbogbo ohun ti Olodumare da, iwo ni o rewa
ju,nitori pe, O da o ni aworan ara re atipe ni bi O se ri gan-an .Olodumare da
o ki o ri bi Oun ki o si maa se bii Oun. Iwo ni ise owo Re ti o peregede, O da
o fun ogo ati ewa Re.
The Minister of Finance and Coordinating Minister of the Economy, Wale Edun,
on Thursday, held a meeting with President Bola Tinubu against the backdrop
of ongoing discussions on a new national minimum wage.
The Minister of Budget and Economic Planning, Atiku Bagudu, was also in
attendance at the meeting which held at the State House in Abuja.
It was gathered that during the meeting, Edun presented a new minimum
wage template to President Tinubu, meeting the 48-hour deadline earlier
issued to him.
The source added that Tinubu is currently reviewing the proposal, and an
official announcement would be made soon.
Our correspondent gathered that the government team may unveil the new
proposal during today’s meeting of the tripartite committee on minimum
wage, which is made up of the government, organized labour, and the
organized private sector.
Previously, the government and the Organized Private Sector had proposed a
minimum wage of ₦60,000, which was outrightly rejected by organized labour
representatives and resulted in the nationwide strike action which rocked the
country on Monday and was eventually suspended on Tuesday after
interventions in which some agreements were signed between the
government and the labour.
Minisita fun eto isuna to tun je alakoso eto oro aje orilẹede yi,
Wale Edun lojo ojobo ose yi ti se ipade pelu Aare Bola Tinubu
Iroyin fi yewa pe, Edun te pepe batani owo osu osise to kere ju
wakati mejidinlaadota.
Akoroyin wa ri gbo pé, o seese ki iko ijoba o siso loju aba owo
waye laarin iko ijoba, asoju egebe osise ati iko osise aladani.
Mimu aba owo osu osise tuntun ohun wa si imuse loje ifarajin
lori oro owo osu osise to kere julo leyi to ti n fa aigbora e niye
Saaju, ni ijoba ati iko agbani sise nileyi ti daba Egberun lona
ogota naira gegebi owo osu osise to kere julo ti àwon asoju
egbe osise nileyi si ko jale pe awon koni gba owo naa lae lae leyi
keta osu kefa, odun 2024 sugbon tiwon pada so iyanselodi naa
ÀSA YORUBA
Àṣà Yorùbá jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ẹ̀yà [Yorùbá] ń lò láti fi gbé èrò, ìmọ̀, àti ìṣe
wípé Àṣà ni ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ìgbé ayé àwọn ènìyàn kan, ní àdúgbò
kan, bẹ̀rẹ̀ lórí èrò, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, ìsẹ̀dá ohun èlò, ìtàn, òfin,
ìṣe, ìrísí, ìhùwàsí, iṣẹ́ -ọnà, oúnjẹ, ọ̀nà ìṣe nǹkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò
kọ̀ọ̀kan padà. Pàtàkì jùlọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, eré ìbílẹ̀, àti iṣẹ́ ìbílẹ̀. Gbogbo àwọn
nǹkan wọ̀nyí ni wọ́ n kó'ra jọ pọ̀ ń jẹ́ àṣà. Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà àti
ìṣe Yorùbá, a ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí a ń mú enu bà ni ìhùwàsí àti ìrísí
wa láàrín
àwùjọ. Nínú ogún-lọ́gọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe tí ó ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan
pàtàkì ni' Àṣà ìkíní nílẹ̀ Yorùbá. Èyí jẹ́ ohun tí gbogbo àwọn ẹ̀yà tí ó kú
"Ẹ kú àárọ̀/Ẹkáàárọ̀,
Nílẹ̀ Yorùbá, gbogbo àsìkò ni ó ní ìkíni tirẹ̀, ṣùgbọ́n ọmọdé ni ó kọ́kọ́ máa ń kí
àgbà. Èyí tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ Yorùbá ní wí pé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò ní ẹ̀kọ́ tàbí,
wọ́n kọ́ ọ ní'lé, kò gbà ni. Bí ó bá jẹ́ ìgbà ayẹ̣ yẹ bíi ìsìnkú àgbà, nítorí Yorùbá
kì í ṣe òkú ọ̀dọ́, ẹhìnkùnlé ni wọ́n máa ń sin òkú ọ̀dọ́ sí. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé, òfò
ni ó jẹ́ fún àwọn òbí irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wàyí, bí ó bá jẹ́ òkú àgbà, wọn á ní, "Ẹ kú ọ̀fọ̀, ẹ
kú ìsìnkú, Olórun yóò mú ọjọ́ jìnnà sí'ra o." Bí ó bá jẹ́ ayẹyẹ
Ìkómojáde/Ìsọmọlórúkọ, wọn á ní, "Ẹ kú ọwọ́lómi o." Bákan náà, oríṣiríṣì àkókò
ni ó wà nínú odún. Àkókó òfìnkìn, Àkókò ọyẹ́, Àkókò oòrùn (Summer),
Àkókò òjò, gbogbo wọ̀nyí sì ni àwọn Yorùbá ní bí a ṣe ń kí'ni fún. Ẹ jẹ́ kí á gbẹ́
àṣà ìsìnkú yẹ̀wò.
Àṣà ìsìnkú nílẹ̀ Yorùbá
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú wípé ó ní àwọn òkú tí Yorùbá máa ń ṣe ayẹyẹ fún, àwọn
bíi òkú àgbà, nítorí wọ́n gbà wí pé, olóògbé lọ sinmi ni, àti wí pé, wọ́n lọ'lé.
Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọjà ni ayé, ṣùgbọ́n ọ̀run ni ilé.
Bí ó bá jẹ́ òkú ọ̀dọ́ tàbí ọmọdé, òkú ọ̀fọ̀ àti ìbànújẹ́ ló jẹ́. Wọ́n á gbà wí pé, àsìkò
rẹ̀ kò tíì tó. Yorùbá máa ń ná owó àti ara sí ìsìnkú àgbà, pàápàá bí olóògbé náà
bá jẹ́ ẹni tí ó ní ipò àti ọlá nígbà tí ó wà láyé, tí ó sì tún bí ọmọ. Ìsìnkú àwọn
wọ̀nyí máa ń lárinrin, ayé á gbọ́, òrun á sì tún mọ̀ pẹ̀lú.
Ní ayé àtijọ́, bí aláwo bá kú, àwọn àwọn Olúwo ní ń sìnkú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wọn á pa
adìyẹ ìrànà, wọn á sì máa tu ìyẹ́ rẹ bí wọ́n ṣe ń gbé òkú rẹ̀ lọ. Lẹ́yìn tí wọn bá
sin òkú tán, àwọn aláwo náà á sun adìye náà jẹ. Ìdí rèé tí Yoòbá fi máa ń sọ wí
pè, "Adìyẹ ìrànà kì í ṣ'ọhun à jẹ gbé." Nítorí pé, kò sí ẹni tí kò ní kú.
Ọ̀fọ̀ ni ó máa ń jẹ́ tí ìyàwó ilé bá sáájú ọkọ rẹ̀ kú. Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọkọ ló
máa ń sáájú aya rẹ̀ kú, kí ìyàwó máa bójú tó àwọn ọmọ. Fún ìdí èyí, bí okùnrin
bá kú, àwọn ìyàwó irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ṣe opó pẹ̀lú ìlànà àti àṣà Yorùbá. Ogójì ọjọ́
tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n máa ń fi ṣe opó. Lẹ́yìn ìsìnkú, àwọn àgbà ilé ni wọ́n máa
pín ogún olóògbé fún àwọn ọmọ rẹ̀, bí ó bá jẹ́ òkú olọ́mọ. Àmọ́ tí kò bá bí’mọ,
àwọn ẹbí rẹ̀, ní pátàkì jùlọ, àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ tí ó jù ú lọ ní wọ́n máa pín ogún
náà láàárín ara wọn. Ó tún jẹ́ àṣà Yorùbá òmíì kí wọn máa ṣú opó olóògbé fún
àwọn àbúrò rẹ̀, láti fi ṣe aya.
Ohun tí ó jẹ́ orírun àṣà ni ‘àrà’, ó lè dára tàbí kí ó burú. Ìpolówó Èkìtì – iyán rere,
ọbẹ̀ rere; Ìpolówó Oǹdó Ẹ̀gi – (dípò Iyán) ẹ̀bà gbọn fẹẹ. Àṣà Oǹdó ni kí wọ́n
máa pe iyán ní ẹ̀bà, nítorí pé èèwọ̀ wọn ni, wọn kò gbọdọ̀ polówó iyán ní àárín
ìlú.
Ìsọ̀rí Àṣà
A lè pín àṣà sí ìsọ̀rí mẹ́ta, èyí tí ó jẹ mọ́:
ilà kíkọ,
irun dídì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Igi gbígbẹ́,
Igbá fínfín
Ilé kíkọ́
Ẹní híhun
Ara dídá /fínfín àti bẹ̀ ẹ́ bẹ̀ ẹ́ lọ.
Àbùdá Àṣà
Lára àbùdá àṣà ni pé:
(a) Kò lè è súyọ láìsí ènìyàn, ìdí ni wípé ẹ̀mí àṣà gùn ju ti ènìyàn lọ.
(a) Àṣà lè jẹyọ nínú oúnjẹ: Òkèlè wọ́pọ̀ nínú oúnjẹ wa. Àkókó
kúndùn ẹ̀bà, Ìlàjẹ fẹ́ràn púpurú,Igbó ọrà kìí sì í fi láfúnòṣèré.
(b) Àṣà lè jẹyọ nínú ìtọ́jú oyún, aláìsà,òkú; ètò ẹbí, àjọṣepọ̀; ètò ìṣàkóso àdúgbò,
abúlé tàbí ara dídá nípa iṣẹ́-ọnà.
Aáyẹ tí ó de bá àṣà
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ,
lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà
wọ̀nyí:
(b) Àyípadà lè wáyé bí àṣà tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ bá dógba pẹ̀lú àṣà tuntun, wọ́n lè jọ
rìn pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àṣà ìgbéyàwó.
(d) Bí àṣà tuntun bá lágbára ju èyí tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, yóò sọ àṣà ti àtẹ̀hìnwá di
ohun ìgbàgbé. Bí àpẹẹrẹ, bí a ṣe ń kọ́'lé.
ÀKÍYÈSI:
Èdè àwọn ènìyàn jẹ́ kókó kan pàtàkì nínú àṣà wọn. Kò sí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò nínú
àṣà àti èdè. Ìbejì ni wọ́n. Ọjọ́ kan náà ni wọ́n délé ayé nítorí pé kò sí ohun tí a fẹ́
sọ nípa àṣà, tí kì í ṣe pé èdè ni a ó fi gbé e kalẹ̀. Láti ara èdè pàápàá ni a ti lè fa
àṣà yọ. A lè fi èdè Yorùbá sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni, a lè fi kọrin, a lè fi kéwì, a lè
fi jọ́sìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láti ara àwọn nǹkan tí à ń sọ jáde lẹ́nu wọ̀nyí ni àṣà wa
ti ń jẹyọ. Ara èdè Yorùbá náà ni òwe àti àwọn àkànlò-èdè gbogbo wà. A lè fa
púpọ̀ nínú àwọn àṣà wa yọ láti ara òwe àti àkànlò èdè.
Nítorí náà, èdè ni ó jẹ́ òpómúléró fún àṣà Yorùbá. Àti wí pé, òun ni ó fà á tí ó fi
jẹ́ pé, bí àwọn ọmọ Odùduwà ṣe tàn kálẹ̀, orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n, èdè kan náà ni
wọ́n ń sọ níbikíbi tí wọ́n lè wà. Ìṣesí, ìhùwàsí, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀. Fún ìdí
èyí, láìsí ènìyàn, kò le è sí àṣà rárá.àsà jẹ́ nnkan gbòógì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè
ṣùgbọ́n àwọn yorùbá mu ní ọ̀kúnkúndùn kí gbogbo wa sì gbe lárugẹ.
Abari
Abari jẹ okan lara awon ounjẹ ilẹ Yoruba to gbajumo nigba kan ri. Sugbon opọ
lara awon omọ aye ode oni ni ko mọ abari yii.
Abari fara jọ moinmoin, sugbon agado ni won fi n ṣe abari dipo ewa.
Ni awọn ẹya kan lorilẹede Naijiria, wọn ma n pe ni Ukpo Oka, Sapala, Oka
Ekusu tabi Ekoki, awọn miiran tun ma n pe nigba Ngwu Oka.
Awọn Yoruba man fi ìgbá si i, bẹẹ ni awọn Igbo ma n fi efirin tabi ẹfọ ugwu si i,
ko le ni orun didun.
Lara awọn eroja ti wọn ma n fi se abari ni agbado, tataṣe, ede, igba, ata gigun,
epo pupa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
2. Egbo
Ewa ati agbado ni Egbo, o si jẹ ounje ilẹ Yoruba.
Bi won se ma n se Egbo ni pe, wọn ma se agbado gbigbe titi ti yoo fi rọ, bakan
naa ni wọn ma se ewa lọtọ.
Won ma n jẹ Egbo pelu ata dindin to ni alubosa, epo pupa, eja yiyan ati tomati
ninu.
Awon elo ti won fi n se egbo ni agbado, ewa, epo pupa, tomati, abubosa, ata,
ati bẹẹ bẹẹ lọ.
3. Aadun
Aadun jẹ ounjẹ ipanu nilẹ Yoruba. Agbado, epo ati awon eroja miiran ni won fi
n ṣe.
Awọn Yoruba ma n lo aadun ni ibi aseyẹ tabi igbeyawo laye atijọ.
Ohun ti wọn fi n se aadun ni; agbado ti wọn ti lọ, epo pupa, iyọ, ati awọn eroja
miiran.
4. ỌjOjọ
Ọjojo jẹ okan gboogi lara awon ounjẹ Yoruba laye atijọ.
Isu ewura ni won fi n se e Ọjọjo.
ọjọjọ dabi akara loju, paapaa ti eeyan ba n wo o lati okere.
Bo tilẹ jẹpe, o le to aadota iseju lati pese Ọjojo, sugbon ko soro lati pese rara.
Awon eelo Ọjọjọ niwonyi: isu ewura, ororo, ata rodo, alubosa, ede, iyọ diẹ, ati
bẹẹ bẹẹ lọ.
5. Isu àti epo tàbí ikete
Iṣu ati epo
Bo tilẹ jẹ pe awon eeyan kan lero pe talaka nikan lo n fi epo jẹisu sugbon ko ri
bẹẹ rara tori ounjẹ to da yatọ ni.
Opolopo awon eeyan ti pa epo ti lati maa fi jẹ isu bayii, ti wọn si ti n lo eyin
dindin, sugbon isu ati epo ma n dun laye atijọ ninu oko.
Awon mii laye atijọ nile Yoruba a maa fi kẹtẹ jẹ isu tori o ni ọpọlọpọ ororo lara.
ẹni ba fẹ gbadun isu ati epo ni lati se isu naa saaju, lẹyin naa ni yoo tọ epo diẹ
sori isu gbigbona naa, o lee fi iyọ diẹ si i.
Àì mò ànfàní àti iyì tí o wà níbi oge ṣíṣe àti ṣíṣe ẹwà ní Ilè Yorùbá ni ìsọ̀rí ohun
ti àwa ọ̀dọ́ ìwòyí ko fi pàtàkì OGE ṢÍṢE.
Ní ayé òde òní tí a bá rí ẹni tí o kò ilà, àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn akẹgbẹ́ re yíò máà fi
se yẹ̀yẹ́ nítorí pé wón ri ilà kíkó gẹ́gẹ́bí ohun ayé àtíjó tí kò ye kí a máà rí ni òde
òní mò, tàbí tí àbá rí ẹni tí o wo agbádá, dànsíkí, bùbá, ìró àti bùbá tàbí ẹni tí o
se àwọn irun bíì ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, kọjúsọ́kọ kẹ̀yìnsálẹ̀, wón a máà wo wón bí ẹni tí
kò rí ookan, béè àwọn ohun tí o n bú ẹwà kún àsà àti isé ilè Yorùbá.
Osùn kíkùn
Làálì Lílé
Etí lílu
Irun dídì
Orí fífá
Ilà kíkọ
a) Làálì Lílé: Àsà làálì lílé jẹ́ ohun tí àwọn Yorùbá kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn Haúsá,
nítorípé àwọ̀n ní wón máà le làálì láti ìbèrè pẹ̀pẹ̀. A ní ewé igi tí a mò sí ewé
laali, a máà ń kún ewé yíì , ao fi káún si, ao si fisí ibi tí a bá fe le làálì náà si ní
ara wa.
b) Tìro Lílé: Tìro nínú tún jẹ́ ohun tí o se pàtàkì nínú ìsaralóge ilè Yorùbá, yàtọ̀
si wípẹ́ a máà n fi tìro se oge, tìro tún dára fún ojú wà, a máà kò ìdọ̀tí kúrò nínú
ojú, a si máà jẹ́ kí ojú rína kedere. Àti okùnrin, àti obìnrin ní o lé le tìro sùgbón
obìnrin ní ó pọ̀jù nínú àwọn tí o máà le tìro.
d) Ilà Kíkọ: Ilà kíkọ jẹ́ ònà tí àwọn Yorùbá fi ń se oge ní ayé àtíjó, àwọn bàbáńlá
wa a máà ko ilà fún ọmọ láti bù ẹwà kún ojú ọmọ náà, wón a sí tún máà ko ilà
fún ọmọ láti fi se ìpín láàrin ọmọ wón àti ọmọ èlòmíràn paapaa jùlọ láàrin ẹ̀yà
kan sí ìkejì, oríṣiríṣi ilà kíkọ ní o wa, ẹ̀yà oríṣiríṣi sí ni o ní bí wón tí se n ko ilà
tiwon, tófi jẹ́ wípẹ́ tí àwọn ènìyàn bá tí rí ilà yi lójú ènìyàn kan, wón tí mò ibi tí
ẹni náà tí wá.
e) Etí Lílu: Etí lílu láti fi se oge jẹ́ ohun tí àwọn obìnrin nìkan gbudọ̀ máà se tí
okùnrin kòsì gbọdọ̀ kópa nípe, Àwọn obìnrin máà n lu eti won lati fi yeri eti sí,
yẹrí etí ti a fi orisirisi iyun ati ilẹ̀kẹ̀ se, tí yíò si máà múwon rẹwà si.
ẹ)Irun dídì: Oríṣiríṣi ara ní àwọn obìnrin Yorùbá máà ń fi irun dá, wón a máà se
irun orí wón láti fi se oge, ní ìgbà míràn, wón a máà fi ilẹ̀kẹ̀ si láti gbẹ́ ẹwà wón
yo dáradára.
f) Irun Fífá: Nígbàtí àwọn obìnrin bá ń di irun wón, àwọn okùnrin náà a máà
fà orí wón, ònà tí o bá wùwón ní wón fi le fà, tí yíò si máà gbẹ́ ẹwà tiwon máà
yo gẹ́gẹ́bí okùnrin. Àyàfi àwọn tí a mò sí Ìlárì ọba, tí wón máà n fi díè le nínú orí
wón láti fi hàn pé ìlárì niwon.
máà gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí i ọkọ àti aya. Àṣà ìgbéyàwó ní ilẹ̀ Yorùbá ṣe kókó,
àwọn Baba ńlá wá bọ̀, wọ́n ní “ìyàwó dùn ún gbé, ọmọ dùn ún kó jáde”.
Oríṣiríṣi ònà ni a le gbà láti gbé iyawo ní èyí tí kò yo ònà tipátipá náà
Oríṣiríṣi Ìgbéyàwó
Ìgbèyawó Àsànte
Ìgbèyawó yi le waye nigbati ọkọ ìyàwó ba n fúra wí pé àwọn òbí ọmọbìrin náà
fé fi ọ̀be ẹ̀yìn jẹ́ òun n’isu, tabi ti o ba rí I pé ojú ọmọbìrin naa ò gbé ibì kan.
Irúfé ìgbéyàwó bayi maa n wáyé nígbàtí ọkọ-ìyàwó yi ba lo ji ìyàwó àfésónà re
gbe yálà nìgbà tí ọmọbìrin naa ba n ti ona.
Èyí maa n wáyé nígbàtí àwọn olólùfé méjì bá ń fé ara wón sùgbón tí àwọn òbí
wón mejeeji kò lówó si tabi ti won kò fe ki won fe ara wón. Báyìí ní àwọn ọkọ
àti ìyàwó yóò bá sálo sí ìlú míiràn láti lo bèrè ìrìn àjò ayé wón láìsí ìyònda àwọn
òbí wón níbè pé kí wón fé ara wón. Léyìn ọdún díè tí wón bá tí sálo , tí wón si tí
bímọ méjì tàbí jù béè lo wón le pinnu àti padà wá si ìlú wón.
Èyí ní irúfé Ìgbéyàwó tí ó sábà máà n wáyé láàrin onísègùn tàbí babaláwo àti
ọmọbìrin. Èyí máà n selè nígbàtí ara ọmọbìrin náà kò bá ya , ti àìsàn tàbí egbò
ńlá kan bá kolùú tí wón si ti náwó-nára sùgbón ti won o rójútu àìsàn náà, tí
wón wà gbẹ̀ lo sí òdò babaláwo tàbí onísègùn kan, tí wón si se ìlérí fún
onísègùn náà pé tí o bá le wo ọmọbìrin náà san, Òun ní ọmọbìrin náà yóò fe
nìgbà tí ara re bá yá.
Ìgbèyawó Òrìsà
Àwọn àgbà bò wón ní wón ni babaláwo ní n s’oko àbíkú. Irúfé Ìgbéyàwó yi má
ń wáyé nígbàtí wón bá wo àkosèjáyé ọmọbìrin ti ifá sí so fún wón pé òrìṣà
funfun ní oko re. Àwọn òbí ọmọ yíì o wà lo gbẹ́ ọmọ náà fún àwọn ọlọ́bàtálá
tàbí òdò babaláwo. Lónà kejì èwè, tí ọmọbìrin bá ti dàgbà tí okùnrin kankan
lósì kọ̀ ẹnu ìfé si rárá.. Tí wón bá lo ye ifá wo, babaláwo le so fún wón pé
ọmọbìrin náà tí l’óko àti wípẹ́ òrìṣà kan ní oko re jẹ́.
TABI
1. ÌFOJÚSÓDE : Ìfojúsòde máà ń wáyé nìgbà tí ebí kan bá n wà ìyàwó fún ọmọ
wón okùnrin tí o tí bàlágà.
2. ÌWÁDÍI : Àwọn Ẹbí ọmọkùrin ń rí ń yóò bẹ̀rẹ̀ síì se ìwádíi nípa ìdílé tí wón tí fé
fé obìnrin , nítorí pé oríṣiríṣi ìdílé lo wà ìdílé míiràn àrùn búburú a máà yo wón
lẹ́nu bi àpẹẹrẹ; àrùn ágànná, wárápá, àbísínwín abbl. Ìdílé míiràn àwọn obìnrin
wón kii gbẹ́ ilé ọkọ dalé, ìdílé míiràn ìgbésì jíje a máà rò wón lórùn, ìdílé míiràn
wón kii dàgbà, wón yóò tún te síwájú láti se ìwádíì irú ènìyàn tí Ọmọbìrin náà jẹ́
bóyá àsà ọmọ ní, bóyá òní kẹ̀bẹ̀kẹ̀bẹ̀ ní, léyìn èyí ní wón yóò wà lo bèèrè lọ̀wò
ifá gẹ́gẹ́ bí Ẹlérì-ìpín tí kò lee puró , gbogbo àṣírí ọjọ́ ọ̀la ìgbéyàwó náà ní yóò
han kẹdẹrẹ láti òdò ifá.
3. ALÁRINÀ : Alárinà jẹ́ okùnrin tàbí obìnrin tí o sùn mò ọmọbìrin , o le jẹ́ ọ̀ré
tàbí mòlébí obìnrin òun ní eni tí o n ye ònà fún ọmọkùrin tí o fé fé ìyàwó kí
àwọn mẹ́jèjì tó pàdé.
4. ÌSÍHÙN: Ìsíhùn ní gbígbọ́ àti gbígbà tí ọmọbìrin gbà láti jẹ́ kí ọmọkùrin náà jẹ́
àfésónà òun. Ọmọkùnrin yíì yóò wà san owó ìsíhùn fún àwọn ẹbí ọmọbìnrin yíì
kí o tó le máà bá ọmọbìnrin náà sòrò, owó náà jẹ́ ọ̀ké kan láyé àtijówòn yóò sí
fi obì àbàtà, ataare, àti orógbó sí owó ìsíhùn náà.
5. ÌTORO : Àwọn òbí àti díè nínú ẹbí Ọmọkùnrin yóò lo sí ilé òbí ọmọbìnrin láti
so fún wón péà wón nìfé sí ọmọ wón obìnrin láti fé. Àwọn òbí ọmọbìnrin yíì
yóò dájọ́ fún àwọn ẹbí Ọmọkùnrin pé kí wón padà wá , o le jẹ́ léyìn ọjọ́ mejé
tàbí jù béè lo, àwọn ẹbí ọmọbìnrin yíì náà yóò lo se ìwádíi nípa irú ìdílé tí
Ọmọkùnrin náà tí jáde, irú ènìyàn tí òun fúnra re jẹ́, wón yóò te síwájú láti se
ìwádíi lọ́wọ́ ifá bí ọjọ́ iwájú ìgbéyàwó náà yoo se rí, tí ìwádíi wón bá yorí siré,
gbígbọ́ àti gbígbà tí àwọn òbí ọmọbìnrin gbà láti fi ọmọ won obìnrin yíì gẹ́gẹ́ bí
aya ní àwọn Yorùbá ń pé ní ÌJỌ́HEN tàbí bàbá gbọ́ ìyá gbọ́.
6. ÌDÁNA : Ìdána jẹ́ fífẹ́ obìnrin nísu lọ́kà, kíkó àwọn ẹrú ìdána lo sí ilé òbí
obìnrin gẹ́gẹ́ bí àsà Yorùbá, àwọn ǹkan ìdána bíì: isu,obì, orógbó,àádùn,
ataare,ìrèké, iyò, epo, oyin,ẹja-ọsàn, àti owó-orí ìyàwó.
7. Ayẹyẹ-Ìgbéyàwó: Ọjọ́ ayẹyẹ ìgbéyàwó jẹ ọjọ́ iyì àti ẹ̀yẹ fún ìyàwó,ọkọ-ìyàwó
àti àwọn ẹbí wón. Ní ìròlé ọjọ́ tí ìyàwó yóò re ilé ọkọ re , léyìn tí ó bá tí múra tán,
yóò lo dágbẹ́re fún àwọn òbí re àti àwọn ẹbí, àkókó yíì ní ìyàwó yóò máà sun
ẹkún ìyàwó láti fi dágbẹ́re , láti fi dúpẹ́ àti láti fi gbà ìre/àdúrà lẹ́nu àwọn òbí àti
ẹbí re, àwọn ọ̀ré re yóò si máà tẹ̀le e bí o tí n sùn ẹkún–ìyàwó kiri wón yóò
máà re e lẹ́kún. Àṣálẹ́ ní yóò tó darí padà si òdò àwọn òbí re, léyìn ìwúre bàbá
yóò fà ìyàwó lẹ́ ọwọ́ obìnrin tí o jẹ́ àgbà nínú awon ebi ọkọ lọ́wọ́, àwọn
ìyàwó-ilé àti àwọn ọ̀ré ìyàwó yóò fi ìlù àti orin tẹ̀lẹ́ e lo sí ilé ọkọ re.
Ọkọ ìyàwó tí gbọdọ̀ kúrò ní ilé kí wón tó mú ìyàwó re dé, èèwò ní ni ilè Yorùbá
ìyàwó kò gbọdọ̀ bá ọkọ re nílé ní alẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó wón, léyìn tí wón bá tí mú
ìyàwó wolé tán ní ọkọ ìyàwó yóò tó wolé wa. Àwọn Ìyàálé ìyàwó yoo bu omi
tutu si ese ìyàwó tuntun lenu ona abawole, ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá nípa èyí ní
wípẹ́ kí ìyàwó le fie se ẹ̀rò wolé ọkọ re.
Léyìn èyí wón yóò dojú igbá gbígbẹ délè kí ìyàwó tuntun fie se fo o, àwọn
Yorùbá ní ìgbàgbọ́ pé iye ònà tí igbá yíì fo sí ní iye ọmọ tí ìyàwó yóò bí, tí o bá
wuu o le má bí to béè tàbí kí ó bí jù béè lo.
8. ÌBÁLÉ: Ọkọ-ìyàwó àti ìyàwó re yóò jo ní ìbálòpọ̀ fún ìgbà àkókó ní alé ọjọ́
ìgbéyàwó wón láti mò bóyá ìyàwó tuntun yíì ko I tii mò okùnrin rí. Àwọn ọ̀bí
ọkọ yóò tité aso funfun sí ori ìbùsùn nínú yàrá ọkọ ìyàwó láti fi gbà ìbálé ìyàwó
re. Iyì ńlá ní fún àwọn òbí ìyàwó tí ọkọ re bá nílé, ó túmò sí wípẹ́ ọmọbìnrin náà
kò tii mò okùnrin rí. Odidi àgbè ẹmu tàbí odidi paali ìsáná,iyán àti ọbè tí o dára
ní àwọn ẹbí ọkọ-ìyàwó yóò gbẹ́ lo fún àwọn òbí iyawo laaro kùtù ọjọ́ kejì láti fi
dúpẹ́ lọ́wọ́ wón wípẹ́ odidi ní wón bá ọmọ wón , èyí ní óúnje ìbálé, ìyàwó yóò
tún gbà owó ìbálé tii se ọ̀ké-méjì lọ́wọ́ ọkọ re. Ìtìjú àti àbùkù ní fún ìyàwó ti ọkọ
re kò b ànílè, ìlàjì agbè ẹmu tàbí ìlàjì paali ìsáná ní àwọn òbí ọkọ ìyàwó yóò fi
ránsẹ́ sí àwọn òbí ìyàwó tí ọkọ re kò b ànílè láti le jẹ́ kí wón mò wípẹ́ ọmọ wón
tí mò okùnrin rí.
9. ÌKỌ́RÙN: Ọjọ́ karùn-ún tí ìyàwó wolé ọkọ re ní yóò tó jáde síta, láti se isé-ilé
àkókó àti láti lo kí àwọn ẹbí ọkọ re. Ojo yíì náà ní yóò jẹ́ ìgbà àkókó tí yóò dáná
ọúnje fún ọkọ re.
Asa igbeyawo je okan Pataki ninuawon asa ti Yoruba n gbe laruge. Igbeyawo
ni asa siso omokunrin ati omobinrin ti won ti balaga paapo gege bi oko ati
iyawo.
PATAKI IGBEYAWO
1 Ki a le maa bi si ki a si maa re si
Ètò ìsọmọlórúkọ
Kí ọjọ́ ìsọmọlórúkọ tó pé, oríṣiríṣi orúkọ ni àwọn Yorùbá máa ń pe ọmọ titun.
Wọ́n á máa pè é ní Tunfulu, Ìkókó, Aròbó, Kóńkólóyọ, Àlejò. Ní ilè Yorùbá, láyé
àtijọ́, ọjọ́ kẹsàn-án ni wọ́n máa ń sọ ọmọkùnrin lórúkọ, ọjọ́ keje ni wọ́n ń sọ
ọmọbìnrin lórúkọ, ọjọ́ kẹjọ ni wọhn sì ń sọ ìbejì ní orúkọ. Ṣùgbọ́n lóde òní, ọjọ́
kẹjọ ni wọ́n ń sọ ọmọ lórúkọ, yálà ọkùnrin, obìnrin tàbí ìbejì.
Orúkọ àmútọ̀runwá
Èyí ni orúkọ tí a fún ọmọ nítorí ọ̀nà tí ọmọ náà gbà wáyé, tàbí àsìkò tí ó wá
sáyé. Àpẹẹrẹ àti ìtumọ̀ wọn ni;
Taiwo- Ọmọ tí a kọ́kọ́ bí nínú ìbejì (òun ni ó kọ́kọ́ tọ́ ayé wò kí èkejì rẹ̀ tó tẹ̀le)
Kehinde- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé Taiwo ní orí ìkúnlè kan.
Ìdòwú- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé ìbejì.
Àlàbá- Ọmọ tí wón bí tẹ̀lé Ìdòwú.
Ìdògbé- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé Àlàbá.
Ìgè- Ọmọ tó fi ẹsẹ̀ wáyé.
Dàda- Ọmọ tí irun orí rẹ̀ ta kókó.
Àjàyí- Ọmọ tó dojú bolẹ̀ nígbà tí a bi. Tí wọhn tún máa ń pè ní ògídí olú[8]
Òjó- Ọmọkùnrin tó gbé ibi rẹ̀ kọ́rùn wáyé.
Àìná- Ọmọbìnrin tó gbé ibi rẹ̀ kọ́rùn wáyé.
Amuṣan- Ọmọkùnrin tí a bí pẹ̀lú iṣan eegun lọ́wọ́ rẹ̀.
Ato- Ọmọbìnrin tí a bí pẹ̀lú iṣan eegun lọ́wọ́ rẹ̀.
Ọmọpe- Ọmọ tí oyún rẹ̀ ju oṣù mẹ́sàn-án lọ.
Ìlòrí- Ọmọ tí ìyá rẹ̀ kò ṣe nǹkan oṣù tó fi lóyún rẹ̀.
Olugbodi- Ọmọ tó ní ìka ẹsè mẹ́fà.
Odu- ọmọ tó ní ìka ọwọ́ mẹ́fà
Ọ̀kẹ́- Ọmọ ti o wa Ninu apo lasiko ti a bi.
Òní- ọmọ tó máa ń ké tọ̀sán tòru.
Ola - omo ti a bi tele oni.
Otunla- omo ti a bi tele Ola.
Orúkọ àbísọ
Èyí ni orúkọ tí wọ́n sọ ọmọ ní ìbámu pèlú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ nígbà tí ìyá ọmọ náà wà
nínú oyún tàbí nígbà tí a bí i. Apẹẹrẹ àwọn orúkọ wọ̀nyí àti ìtumọ̀ rẹ̀ ni;
Orúkọ Àbíkú
Orúkọ àbíkú ni àwọn orúkọ tó fi ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn nípa àbíkú, àjíǹde, àti
àṣẹ̀yìnwá hàn. Àpẹẹrẹ àti ìtumọ̀ ni:
Orúkọ Oríkì
Àṣà Yorùbá ni láti máa fún ọmọ ní . Gbààrà tí a bá ti sọ ọmọ náà lórúkọ ni a ó
fún un lóríkì. Orúkọ yìí ni wọ́n á fi máa kí ọmọ náà kí orí rẹ̀ ba lè máa wú[17].
Àlàmú
Àrẹ̀mú
Ìṣọlá
Àkànní
Àlàbí
Àjàní
Àkànmú
Àkànbí
Àdìsá
Àlàó
Àlàdé
Àjàó
Àkànjí
Àyìkẹ́
Àríkẹ́
Àpèkẹ́
Àbẹ̀kẹ́
Àdùkẹ́
Àwèró
Àyọ̀ká
Àjíkẹ́
Àbẹ́ní
Àṣàbí
Àjọkẹ́
Àkànkẹ́
Orúkọ Ìnagijẹ
Èyí ò sí lára àwọn orúkọ tí Yorùbá máa ń sọ ọmọ níjọ kẹjọ. Àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí ló
máa ń fún ènìyàn ni irúfẹ́ orúkọ yìí. Ó jẹ́ orúkọ tó máa ń wáyé nípa ìrísí, ìṣesí àti
ìrìnsí ẹni tí a fẹ́ fún ní orúkọ yìí. Apẹẹrẹ:
Eyínfúnjowó
Eyinafé
Àjílàrán
Ajísafé
Òpéléngé
Aríkúyerí
Agbótikúyò
Awéléwà
Eyínménugún
Ìbàdíìlèkè
Ìbàdíàràn
Adúláwò
ORIRUN/ORISUN YORUBA
Awon orirun eni tumo si baba-nla eni, ti o se iran eni sile tabi ori eni ti
iran kan ti bere. Ko si iran kan ni ile Yoruba ti ko ni awon ti o see nitori pe
‘okun ki i gun titi ki o ma ni ibi ti o ti fa wa.
Awon Yoruba gbagbo pe odo ki san ki o gbagbe orisun re, opolopo igba
ni won maa n pe oruko baba-nla won fun iyonu ati aabo nitori pe won
gbagbo pe eni to ba ti ku ni agbara nla lati bukun awon ti won je iran
won ni aye.
Akoko odun tabi loorekoore ni a maa n se etutu lati tu awon orirun eni
loju fun oore ti won n reti lodo won.
Odoodun ni awon iran miiran maa n bo orirun won tabi nigba ti wahala
tabi idarudapo ba wa ninu ebi won.
Orisiirisii ohun jije ati mimu ni won fi ma n bo orirun eni, agbo tabi
agutan adie abbl. Won yoo si ro eje re si oju oori orisun won naa, won
yoo da obi, ti o ba si ti yan, o ti gba niyen, akoko ayeye ni o maa n je fun
gbogbo ebi.
Ni ile Ijebu, Agemo ni won nse. Awon ti ipinle Eko kii fi Adamu – Orisa
sere. (Eyo)
Ila oju, oriki –orile ati isesi iran kookan je eyi ti a fi n da ara wa mo, ti o si
n mu orirun eni wa si iranti.
Inu oriki-orile ise, ise, iwa, esin, ati eewo iran ni a ti n gbo oniruuru oruko
ti awon baba-nla wa ti je seyin. Apeere:
Iran onikoyi je iran jagun jagun, eyi si han ninu oriki ati itan iran won,
baba –nla won je jagunjagun. Iwa akin hihu ko si fi iran yii sile.
ETO EBI
Ni ile Yoruba, ebi ni a tun n pe ni alajobi tabi molebi. Alajobi ni iya, baba,
egbon, aburo ati ibatan eni ni apapo. Eto ebi ni opomulero ti o gbe asa,
ise, ati ibara-eni-gbepo awon Yoruba duro. omo nibi-niran ni awon
Yoruba. Bi won se tan si ile baba ni won tan si ile iya.
Eto ebi bere lati inu ile. Gege bi asa baba ni olori ile, iya ni atele ki o kan
awon omo gege bi ojo ori won. Iko kokan ni o ni ipa ti o n ko lati mu ki
ife, isokan, laafia ati ajosepo wa ninu ebi.
Ipo Orogun
Àwọn ọmọ ènìyàn gbà wí pé ọlọ́run tóbi ju gbogbo ẹ̀dá lọ ó sì jẹ ẹni tí wọ́n
gbọ́dọ̀ má a bọlá fún, èrò ọkàn àwọn Yorùbá ni pé ọlọ́run tàbí olódùmarè tóbi
púpọ̀, ó sì ju ẹnikẹ́ni lọ àti nítorí èyí kò yẹ kí wọ́n máa dárúko mọ́ ọ lórí bí wọ́n ti
ń ṣe sí ẹgbẹ́ àti ọ̀gbà wọn, láti bu ọlá fún-un àti láti fi ìtẹríba wọn hàn fún un
wọ́n ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ pè é, wọn a ní ẹlẹda, èyí ní ẹni tí ó dá ọ̀run, àti ayé, òyígíyigì,
èyí ni ẹni tí ó tóbi tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò sí ohun tí a lè fi wé. Ọba àwámárìdí, èyí ni ẹni
tí a kò lè rí ìdí iṣẹ́ rẹ̀, Alábàláṣe, èyí ni ẹnì tí ó ni àbá àti àṣẹ, Bàbá, èyí ni baba
gbogbo ẹ̀dá inú ayé, Ọ̀gá ògo; èyí ni ẹni tí ó ni ọ̀run èyí tí ó jẹ́ ògo ẹ̀dá tàbí
nígbà mìíràn a lè túmọ̀ rẹ̀ sí ẹni tí ògo tàbí ìgbéga ẹ̀dá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀,
Atẹ́rẹrẹkáríaye, èyí ni ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní gbogbo ayé ní ìkáwọ́ rẹ̀, ẹlẹ́mìí, èyí ni
ẹni tí ó ni ẹ̀mí ẹ̀dá.
Bí a bá tún gbó nígbà mìíràn tí àwọn àgbàlagbà ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘Èdùàrè tàbí
wọ́n ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘olú’ olódùmarè kan náà ni wọn ń tọ́ka sí. Àwọn
àgbàlagbà a máa sọ pé:
mo ló dàṣegbé
Ohun tí àkọlé yìí ń tọ́ka sí ni pé ohun tí ọmọ Èdùàrè, èyí tí ó dúró fún
olódùmarè bá ti ṣe àṣegbé ni ìgbà gbogbo là ń gbọ́ tí àwọn àgbàlagbà máa ń
sọ pé “ẹni olúwa dá kò ṣe é fara wé”. Ohun tí wọn ń tọ́ka sí nínú gbólóhùn yìí
nip é ẹni tí Olú, èyí tí ó dúró fún olódùmarè “bá ti dá àyànmọ́ kan mọ́ ẹnìkan, a
kò lè fara wé irú ẹ̀nìyàn bẹ́ẹ̀.
Olódùmarè náà ni Ọba àìrí, àwámárìdí Yorùbá tún gbà pé ó jẹ Ọba mímọ́ tí kò
léèérí, alálà funfun òkè. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé bí àwọn áńgẹ́lì tí jẹ́ Olùrànláwọ́
fún Olódùmarè lóde ọ̀run ni àwọn òrìṣà náà jẹ́ aṣojú rẹ̀ lóde ìṣálayé, àwọn
òrìṣà wọ̀nyí jẹ́ alágbàwí àwọn ènìyàn níwájú olódùmarè. A gbọ́ wí pé ìbáṣepọ̀
wà láàárin àwọn òrìṣà tàbí òòṣà ilẹ̀ Yorùbá àti Olódùmarè, àwọn Yorùbá
gbàgbọ́ pe òòṣà wọ̀nyí nì wọ́n lè rán sí olódùmarè yálà láti tọrọ nǹkankan lọ́wọ́
rẹ̀ tàbí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ohun ribiribi tí ó ṣe fún wọn. Erò yìí hàn nínú òwe
Yorùbá kan pé “ẹni mojú ọwá là ń bẹ̀ sọ́wá, olójú ọwá kan kò sí bíkòṣe ayaba”.
Ìdí nìyí tí ó fi jẹ pé bí a bá fẹ́ kí Ọba ṣe ohun kan fún ni a ó bẹ ayaba sí i, ipò
alágbàwí láàárin àwọn abòòṣà àti olódùmarè ni àwọn òòṣà wà.
Paapaa wọn ni igbagbọ wi pe awọn orisa yii dabi angẹli tabi iranṣẹ olodumare
ti awọn eniyan ma n pe ni igba iṣoro.
Lara awọn orisa naa ni Esu, Ogun, Ọbatala, Yemọja, Osun, Sango ati Ọya, ti
wọn pe ni Ọrumila.
Esu
Ni ile Yoruba, awon ̣ elesin ibilẹgbagbo wi pe esu je orisa to lagbara pupo, to
si je iranse laarin aye ati orun, to fi mo agbede meji.
Oun si ni ọkan lara awon orisa ti o ma n tọ awon oku sọna lẹyin ti wọn papoda.
Wọn gbagbọ wipe esu ni a n ke pe ti ohun ba daru, ti eniyan si n wa ọna abayọ
tabi ojutu si nkan to wo.
Bakan naa ni wọn ri ęmi esu gẹgẹ bi orisa alarekereke, to seese ko tan eniyan
jẹ.
Awon asọ pupa ati dudu ni o jọ mọ orisa yii, ti wọn si n lo ata wẹwę, taba
mimu ati ounjẹ gbigbona lati fi bọ orisa yii.
Ogun
Ogun jẹ orisa akunlẹbọ ti wọn gbagbọ wi pe oun ni ęni keji to lagbara julọ ninu
awọn orisa meje to ku.
Ogun ti gbogbo eniyan mọ pęlu irin, ni o ma n sisẹ iwosan to si je oba lori
gbogbo ohun ti a fi irin da.
Awon ęlęsin ibilẹ gbagbọ wipe abiyamọ tootọ ni Ogun, ti o ma n se atilẹyin fun
omode ati idile. Oun si ni won n pe lati bura tabi rin irinajo.
Won gbagbọ wipe orisa kan ti kii sinmi ni Ogun jẹ, to si ma n fi ẹjẹ wẹ bi omi.
Amo, ęnikęnị ti ęję ba n yọ ni ara rẹ ko gbodọ sunmo idi orisa Ogun.
Lati bọ Ogun, won ma n lo ewe ni ẹba titi, irin, ęjẹ, awon ohun ija, ęran,
ogogoro ati bęę bęęlọ.
Ọbatala
Ọbatala jẹ okan lara awon orisa meje ti o tutu pelu ebun itusilẹ ati alaafia.
Amọ, oun ni awon olorisa gbagbọ wi pe o ma n da awon eniyan ti ko pe,
paapaa awon akanda eniyan.
Ọbatala ni o ni suuru julọ laarin awon emi meje yii, to si ma n ṣe idajọ ododo.
Orisa yii fẹran awon eniyan ti kii se alara gbigbona, ti won si le e ko ara won ni
ijanu.
Asọ funfun ni a mọ pelu Ọbatala, ti o si ma n sisẹ iwosan fun awon to ba ni
ailera, paapaa awon akanda eda.
Bẹẹ si ni Ọbatala kii gba oti kikan rara, yatọ si omi, miliki, suga, ogedẹ ati
bęębęęlọ.
Yemọja
Yemoja jẹ obinrin lara awon orisa meje to di ile aye mu, to n gbe ninu omi, to si
n ję oba lori gbogbo omi nla nla.
Yemoja to jẹ ęja nla ninu odo ni ibatan Osun to ję oba lori awon omi keekeeke.
Awon ęlęsin ibilẹ gbagbọ wipe olupese ni Yemoja, to n pese Omo, to si n fun
awon eniyan ni ohun meremere ninu omi, amọ o si le e fa ibinu yọ bi ękun omi
tabi iji lile.
Lailai, Oya ati Yemọja kii se orẹ nitori naa won kii gbe won si ibi kan naa.
Awon arinrinajo lori omi ma n bọodo, ki wọn to bęrẹ irinajo won, ki o le lo ni
irowọ-rosẹ.
Ọsun
Orisa akunlębọ yii ni awon ęlęsin ibilẹ gbagbọ wipe o ję oba lori awon omi
keekeeke, to si jẹ ibatan Yemoja.
Ọsun ni wọn ma n bọ ti wọn ba n wa nkan ayo, paapaa omọ tuntun jojolo.
Ọsun kii tete binu, amọ ibinu rẹ ko sunwon rara.
Awon eroja ti won fi n bo Osun ni omi, miliki, oyin ati bẹẹbẹẹlọ.
Ṣango
Ṣango jẹ okan lara awon orisa to gbona janhin janhin, to si ma n rọojo ina ti
irin ba k’oju irin.
Ṣango ni awon ęlęsin ibilẹ gbagbọ wi pe o jẹoko Ọya ati Ọsun.
Ṣango ati Ogun kii ri ara won s’oju rara nitori won kii se orẹ koda ota orun o
gbebo ni won n se.
Ṣango ni o ma n se idajọ nipa lilo monamona, ti kii si jẹ ki ibi sęlẹ si awon
ololufẹrę, to si fęran obinrin, orin ati igbadun.
Ọya
Ọya lo kęyin ninu awon orisa meje to lagbara julọ lagbaye, ti won si ma n fi n
ropo orunmila nigba miran.
Awon ęlęsin ibilẹ gbagbo wipe obinrin to rẹwa ni, ti o si wa ninu omi pęlu
agbara lati sisẹ iwosan ati omọ bibi.
Eewọ ni lati pe orisa Ọya, Yemọja ati Ọsun papọ lęękan naa, nitoripe ota ni
won, won kii ri Ọya s’oju, afi ti ẹba n pe awon orisa mejeeje papọ ni igba kan
naa loku.